Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:2 - Bibeli Mimọ

2 A si sọ fun ọba Jeriko pe, Kiyesi i, awọn ọkunrin kan ninu awọn ọmọ Israeli dé ihinyi li alẹ yi lati rìn ilẹ yi wò.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Àwọn kan bá lọ sọ fún ọba Jẹriko pé, “Àwọn ọkunrin kan, lára àwọn ọmọ Israẹli, wá sí ibí ní alẹ́ yìí láti ṣe amí ilẹ̀ yìí.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 A sì sọ fún ọba Jeriko, “Wò ó! Àwọn ará Israẹli kan wá ibí ní alẹ́ yìí láti wá yọ́ ilẹ̀ yí wò.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:2
7 Iomraidhean Croise  

BIKOṢEPE Oluwa ba kọ́ ile na, awọn ti nkọ́ ọ nṣiṣẹ lasan: bikoṣepe Oluwa ba pa ilu mọ́, oluṣọ ji lasan.


Kò si ọgbọ́n, kò si imoye, tabi ìgbimọ si Oluwa.


Lõtọ, ki ọjọ ki o to wà, Emi na ni, ko si si ẹniti o le gbani kuro li ọwọ́ mi: emi o ṣiṣẹ, tani o le yi i pada?


Gbogbo awọn araiye li a si kà si bi ohun asan, on a si ma ṣe gẹgẹ bi o ti wù u ninu ogun ọrun, ati larin awọn araiye: kò si si ẹniti idá ọwọ rẹ̀ duro, tabi ẹniti iwi fun u pe, Kini iwọ nṣe nì?


JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.


Ọba Jeriko si ranṣẹ si Rahabu, wipe, Mú awọn ọkunrin nì ti o tọ̀ ọ wá, ti o wọ̀ inu ile rẹ jade wá: nitori nwọn wá lati rìn gbogbo ilẹ yi wò.


Awọn ọmọ Dani si rán ọkunrin marun ninu idile wọn lati àgbegbe wọn wá, awọn ọkunrin alagbara, lati Sora, ati Eṣtaolu lọ, lati lọ ṣe amí ilẹ na, ati lati rìn i wò; nwọn si wi fun wọn pe, Ẹ lọ rìn ilẹ na wò: nwọn si dé ilẹ òke Efraimu, si ile Mika, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan