Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 2:1 - Bibeli Mimọ

1 JOṢUA ọmọ Nuni si rán ọkunrin meji jade lati Ṣittimu yọ lọ ṣe amí, wipe, Ẹ lọ iwò ilẹ na, ati Jeriko. Nwọn si lọ, nwọn si dé ile panṣaga kan, ti a npè ni Rahabu, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn náà, Joṣua ọmọ Nuni rán amí meji láti Akasia, lọ sí Jẹriko, ó ní, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá jùlọ, ìlú Jẹriko.” Wọ́n bá lọ, wọ́n sì dé sí ilé aṣẹ́wó kan, tí orúkọ rẹ̀ ń jẹ́ Rahabu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà náà ni Joṣua ọmọ Nuni rán àwọn ayọ́lẹ̀wò méjì jáde ní àṣírí láti Ṣittimu. Ó sì wí pé, “Ẹ lọ wo ilẹ̀ náà, pàápàá Jeriko.” Wọ́n sì lọ, wọ́n wọ ilé panṣágà kan, tí à ń pè ní Rahabu wọ́n sì dúró síbẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 2:1
23 Iomraidhean Croise  

Ẹ rán ẹnikan ninu nyin, ki o si mú arakunrin nyin wá, a o si pa nyin mọ́ ninu túbu, ki a le ridi ọ̀rọ nyin, bi otitọ wà ninu nyin: bikoṣe bẹ̃, ẹmi Farao bi amí ki ẹnyin iṣe.


Josefu si ranti alá wọnni ti o ti lá si wọn, o si wi fun wọn pe, Amí li ẹnyin; lati ri ìhoho ilẹ yi li ẹnyin ṣe wá.


Enia mi, ranti nisisiyi ohun ti Balaki ọba Moabu gbèro, ati ohun ti Balaamu ọmọ Beori dá a lohùn lati Ṣittimu titi de Gilgali; ki ẹ ba le mọ̀ ododo Oluwa.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Rán enia, ki nwọn ki o si ṣe amí ilẹ Kenaani, ti mo fi fun awọn ọmọ Israeli: ọkunrin kan ni ki ẹnyin ki o rán ninu ẹ̀ya awọn baba wọn, ki olukuluku ki o jẹ́ ijoye ninu wọn.


ISRAELI si joko ni Ṣittimu, awọn enia na si bẹ̀rẹsi iṣe panṣaga pẹlu awọn ọmọbinrin Moabu:


Nwọn si dó si ẹba Jordani, lati Beti-jeṣimotu titi dé Abeli-ṣittimu ni pẹtẹlẹ̀ Moabu.


Salmoni si bí Boasi ti Rakabu; Boasi si bí Obedi ti Rutu; Obedi si bí Jesse;


Wo o, mo rán nyin lọ gẹgẹ bi agutan sãrin ikõkò; nitorina ki ẹnyin ki o gbọ́n bi ejò, ki ẹ si ṣe oniwà tutù bi àdaba.


Nitori ẹnyin mọ̀ eyi daju pe, kò si panṣaga, tabi alaimọ́ enia, tabi olojukòkoro, ti iṣe olubọriṣa, ti yio ni ini kan ni ijọba Kristi ati ti Ọlọrun.


Nipa igbagbọ́ ni Rahabu panṣaga kò ṣegbé pẹlu awọn ti kò gbọran, nigbati o tẹwọgbà awọn amí li alafia.


Gẹgẹ bẹ̃ pẹlu kí a ha dá Rahabu panṣaga lare nipa iṣẹ, nigbati o gbà awọn onṣẹ, ti o si rán wọn jade gba ọ̀na miran?


Ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ti o ba tapá si ofin rẹ, ti ki yio si gbọ́ ọ̀rọ rẹ li ohun gbogbo ti iwọ palaṣẹ fun u, pipa li a o pa a: kìki ki iwọ ṣe giri ki o si mu àiya le.


A si sọ fun ọba Jeriko pe, Kiyesi i, awọn ọkunrin kan ninu awọn ọmọ Israeli dé ihinyi li alẹ yi lati rìn ilẹ yi wò.


Helkati pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Rehobu pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹrin.


JOṢUA si dide ni kùtukutu owurọ̀, nwọn si ṣí kuro ni Ṣittimu, nwọn si dé Jordani, on ati gbogbo awọn ọmọ Israeli; nwọn si sùn sibẹ̀ ki nwọn ki o to gòke odò.


Awọn ọmọ Israeli si dó ni Gilgali; nwọn si ṣe ajọ irekọja li ọjọ́ kẹrinla oṣù li ọjọ́ alẹ, ni pẹtẹlẹ̀ Jeriko.


Awọn ara ile Josefu rán amí lọ si Beti-eli. (Orukọ ilu na ni ìgba atijọ rí si ni Lusi.)


Nigbana li awọn ọkunrin marun ti a rán ti o ti lọ ṣe amí ilẹ Laiṣi dahùn, nwọn si wi fun awọn arakunrin wọn pe, Ẹ mọ̀ pe efodu kan wà ninu ile wọnyi, ati terafimu, ati ere fifin, ati ere didà? njẹ nitorina ẹ rò eyiti ẹnyin o ṣe.


Awọn ọkunrin marun ti o ti lọ iṣe amí ilẹ na gòke lọ, nwọn si wá si ibẹ̀ na, nwọn si kó ere fifin, ati efodu, ati terafimu, ati ere didà na: alufa na si duro li ẹnu-ọ̀na pẹlu awọn ẹgbẹta ọkunrin ti o hamọra ogun.


Awọn ọmọ Dani si rán ọkunrin marun ninu idile wọn lati àgbegbe wọn wá, awọn ọkunrin alagbara, lati Sora, ati Eṣtaolu lọ, lati lọ ṣe amí ilẹ na, ati lati rìn i wò; nwọn si wi fun wọn pe, Ẹ lọ rìn ilẹ na wò: nwọn si dé ilẹ òke Efraimu, si ile Mika, nwọn si wọ̀ nibẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan