Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 18:7 - Bibeli Mimọ

7 Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

7 Àwọn ẹ̀yà Lefi kò ní ba yín pín ilẹ̀ nítorí iṣẹ́ alufaa OLUWA ni ìpín tiwọn. Ẹ̀yà Gadi ati ti Reubẹni ati ìdajì ẹ̀yà Manase ti gba ìpín tiwọn tí Mose, iranṣẹ OLUWA, fún wọn ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

7 Ṣùgbọ́n àwọn ọmọ Lefi kò ní ìpín ní àárín yín, nítorí iṣẹ́ àlùfáà. Olúwa ni ìní wọ́n. Gadi, Reubeni àti ìdajì ẹ̀yà Manase, ti gba ìní wọn ní ìhà ìlà-oòrùn Jordani. Mose ìránṣẹ́ Olúwa ti fi fún wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 18:7
11 Iomraidhean Croise  

OLUWA si sọ fun Aaroni pe, Iwọ ki yio ní iní ninu ilẹ wọn, bẹ̃ni iwọ ki yio ní ipín lãrin wọn: Emi ni ipín rẹ ati iní rẹ lãrin awọn ọmọ Israeli.


Ṣugbọn awọn ọmọ Lefi ni ki o ma ṣe iṣẹ-ìsin agọ́ ajọ, awọn ni yio si ma rù ẹ̀ṣẹ wọn: ìlana lailai ni ni iran-iran nyin, ati lãrin awọn ọmọ Israeli, nwọn kò gbọdọ ní ilẹ-iní.


Iwọ ati awọn ọmọ rẹ pẹlu rẹ ni yio si ma ṣe itọju iṣẹ-alufa nyin niti ohun gbogbo ti iṣe ti pẹpẹ, ati ti inu aṣọ-ikele: ẹnyin o si ma sìn: emi ti fi iṣẹ-alufa nyin fun nyin, bi iṣẹ-ìsin ẹ̀bun: alejò ti o ba si sunmọtosi li a o pa.


Nitorina ni Lefi kò ṣe ní ipín tabi iní pẹlu awọn arakunrin rẹ̀; OLUWA ni iní rẹ̀, gẹgẹ bi OLUWA Ọlọrun ti ṣe ileri fun u.)


Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.


Ṣugbọn ẹ̀ya Lefi ni Mose kò fi ilẹ-iní fun: OLUWA, Ọlọrun Israeli, ni iní wọn, gẹgẹ bi o ti wi fun wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan