Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 18:6 - Bibeli Mimọ

6 Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Ẹ óo ṣe àkọsílẹ̀ ìpín mejeeje, ẹ óo sì mú un tọ̀ mí wá. N óo ba yín ṣẹ́ gègé lórí wọn níhìn-ín, níwájú OLUWA Ọlọrun wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 Lẹ́yìn ìgbà tí ẹ bá kọ àpèjúwe ọ̀nà méjèèje ilẹ̀ náà, ẹ mú wọn wá sí ọ̀dọ̀ mi ní ibí, èmi ó sì ṣẹ́ kèké fún yín ní iwájú Olúwa Ọlọ́run wa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 18:6
11 Iomraidhean Croise  

Pe, iwọ li emi o fi ilẹ Kenaani fun, ipin ilẹ-ini nyin.


A ṣẹ́ keke dà si iṣẹpo aṣọ; ṣugbọn gbogbo idajọ rẹ̀ lọwọ Oluwa ni.


Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.


Ki ẹnyin ki o si fi keké pín ilẹ na ni iní fun awọn idile nyin; fun ọ̀pọ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní pupọ̀ fun, ati fun diẹ ni ki ẹnyin ki o fi ilẹ-iní diẹ fun: ki ilẹ-iní olukuluku ki o jẹ́ ibiti keké rẹ̀ ba bọ́ si; gẹgẹ bi ẹ̀ya awọn baba nyin ni ki ẹnyin ki o ní i.


Mose si paṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, wipe, Eyi ni ilẹ na ti ẹnyin o fi keké gbà ni iní, ti OLUWA paṣẹ lati fi fun ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya nì:


Nigbati o si ti run orilẹ-ède meje ni ilẹ Kenaani, o si fi ilẹ wọn fun wọn ni ini fun iwọn ãdọta-le-ni-irinwo ọdun.


Keké ni nwọn fi ní ilẹ-iní wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá, fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya ni.


Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn.


Nitoriti awọn ọmọ Lefi kò ní ipín lãrin nyin; nitori iṣẹ-alufa OLUWA ni iní wọn: ati Gadi, ati Reubeni, ati àbọ ẹ̀ya Manasse, ti gbà ilẹ-iní wọn na ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun wọn.


Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan