Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 18:3 - Bibeli Mimọ

3 Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Joṣua bá sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Ìgbà wo ni ẹ fẹ́ dúró dà kí ẹ tó lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun àwọn baba yín ti fun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Báyìí ni Joṣua sọ fún àwọn ọmọ Israẹli: “Báwo ni ẹ̀yin yóò ṣe dúró pẹ́ tó, kí ẹ tó gba ilẹ̀ ìní tí Olúwa Ọlọ́run àwọn baba yín ti fi fún yín?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 18:3
15 Iomraidhean Croise  

Ẹniti o ba dẹ̀ ọwọ a di talaka; ṣugbọn ọwọ awọn alãpọn ni imu ọlà wá.


Ọkàn ọlẹ nfẹ, kò si ri nkan; ṣugbọn ọkàn awọn alãpọn li a o mu sanra.


Ọna ọlẹ dabi igbo ẹgún; ṣugbọn ọ̀na olododo já gẽrege ni.


Ohunkohun ti ọwọ rẹ ri ni ṣiṣe, fi agbara rẹ ṣe e; nitoriti kò si ete, bẹ̃ni kò si ìmọ, tabi ọgbọ́n, ni isa-okú nibiti iwọ nrè.


Li ọjọ na a o wi fun Jerusalemu pe, Iwọ má bẹ̀ru: ati fun Sioni pe, Má jẹ ki ọwọ́ rẹ ki o dẹ̀.


O si jade lọ lakokò wakati kọkanla ọjọ, o ri awọn alairiṣe miran ti o duro, o si wi fun wọn pe, Ẽṣe ti ẹnyin fi duro lati onimoni li airiṣe?


Ẹ máṣe ṣiṣẹ fun onjẹ ti iṣegbé, ṣugbọn fun onjẹ ti iwà ti di ìye ainipẹkun, eyiti Ọmọ-enia yio fifun nyin: nitoripe on ni, ani Ọlọrun Baba ti fi edidi dí.


Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.


JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.


Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn.


Ẹ yàn ọkunrin mẹta fun ẹ̀ya kọkan: emi o si rán wọn, nwọn o si dide, nwọn o si là ilẹ na já, nwọn o si ṣe apejuwe rẹ̀ gẹgẹ bi ilẹ-iní wọn; ki nwọn ki o si pada tọ̀ mi wá.


Nwọn si wipe, Ẹ dide, ki awa ki o tọ̀ wọn: nitoriti awa ri ilẹ na, si kiyesi i, o dara gidigidi: ẹ dakẹ ni? ẹ má ṣe lọra lati lọ, ati lati wọ̀ ibẹ̀ lọ gbà ilẹ na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan