Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 18:16 - Bibeli Mimọ

16 Àla na si sọkalẹ lọ si ipẹkun òke ti mbẹ niwaju afonifoji ọmọ Hinnomu, ti o si mbẹ ni afonifoji Refaimu ni ìha ariwa; o si sọkalẹ lọ si afonifoji Hinnomu, si apa Jebusi ni ìha gusù, o si sọkalẹ lọ si Eni-rogeli;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 kí ó tó yípo lọ sí ìsàlẹ̀, sí ẹsẹ̀ òkè tí ó dojú kọ àfonífojì ọmọ Hinomu, níbi tí àfonífojì Refaimu pin sí ní ìhà àríwá. Ààlà náà la àfonífojì Hinomu kọjá lọ sí apá ìhà gúsù ní etí Jebusi, ó tún lọ sí ìsàlẹ̀ títí dé Enrogeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ààlà náà lọ sí ìsàlẹ̀ ẹsẹ̀ òkè tí ó kọjú sí Àfonífojì Beni-Hinnomu, àríwá Àfonífojì Refaimu O sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Àfonífojì Hinnomu sí apá gúúsù gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ òkè ìlú Jebusi, ó sì lọ bẹ́ẹ̀ títí dé En-Rogeli.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 18:16
19 Iomraidhean Croise  

Jonatani ati Ahimaasi si duro ni Enrogeli; ọdọmọdebirin kan si lọ, o si sọ fun wọn; awọn si lọ nwọn sọ fun Dafidi ọba nitoripe ki a má ba ri wọn pe nwọn wọ ilu.


Awọn Filistini si wá, nwọn si tẹ́ ara wọn li afonifoji Refaimu.


Adonijah si pa agutan ati malu ati ẹran ọ̀sin ti o sanra nibi okuta Soheleti, ti mbẹ lẹba Enrogeli, o si pè gbogbo awọn arakunrin rẹ̀, awọn ọmọ ọba, ati gbogbo ọkunrin Juda, iranṣẹ ọba:


On si sọ Tofeti di ẽri, ti mbẹ ni afonifojì awọn ọmọ Hinnomu, ki ẹnikan ki o máṣe mu ọmọ rẹ̀ ọkunrin, tabi ọmọ rẹ̀ obinrin là ãrin iná kọja fun Moleki.


Awọn ara Filistia si wá, nwọn si tẹ ara wọn ni afonifoji Refaimu.


O si sun turari li àfonifoji ọmọ Hinnomu, o si sun awọn ọmọ rẹ̀ ninu iná bi ohun-irira awọn orilẹ-ède, ti Oluwa ti le jade niwaju awọn ọmọ Israeli.


O si mu ki awọn ọmọ rẹ̀ ki o kọja lãrin iná àfonifoji ọmọ Hinnomu: ati pẹlu o nṣe akiyesi afọṣẹ, o si nlò alupayida, o si nṣe ajẹ́, o si mba okú lò, ati pẹlu oṣó: o ṣe buburu pupọ̀ li oju Oluwa lati mu u binu.


Nitori a ti yàn Tofeti lati igbà atijọ; nitõtọ, ọba li a ti pèse rẹ̀ fun; o ti ṣe e ki o jìn, ki o si gbòro: okiti rẹ̀ ni iná ati igi pupọ; emi Oluwa, bi iṣàn imí-ọjọ́ ntàn iná ràn a.


Ki o si wi fun wọn pe, Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi: Bẹ̃ gẹgẹ li emi o fọ enia yi ati ilu yi, bi a ti ifọ ohun-èlo amọkoko, ti ẹnikan kò le tun ṣe mọ, nwọn o si sin wọn ni Tofeti, nitoriti aye kò si lati sinkú.


Ki o si lọ si afonifoji ọmọ Hinnomu ti o wà niwaju ẹnu-bode Harsiti, nibẹ ni ki o si kede gbogbo ọ̀rọ ti emi o sọ fun ọ.


Nitorina, sa wò o, ọjọ mbọ̀, li Oluwa wi, a kì yio pe orukọ ibi yi ni Tofeti mọ, tabi afonifoji ọmọ Hinnomu, ṣugbọn Afonifoji ipakupa.


Nwọn si kọ́ ibi giga Baali, ti o wà ni afonifoji ọmọ Hinnomu, lati fi awọn ọmọkunrin wọn ati awọn ọmọbinrin wọn fun Moleki; ti emi kò paṣẹ fun wọn, bẹ̃ni kò wá si ọkàn mi, pe ki nwọn ki o mã ṣe ohun irira yi, lati mu Juda ṣẹ̀.


Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.


Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.


Awọn ọmọ Benjamini kò si lé awọn Jebusi ti ngbé Jerusalemu jade; ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Benjamini gbé ni Jerusalemu titi di oni.


Awọn ọmọ Juda si bá Jerusalemu jà, nwọn si kó o, nwọn si fi oju idà kọlù u, nwọn si tinabọ ilu na.


Ọkunrin na si kọ̀ lati sùn, o si dide o si lọ, o si dé ọkankan Jebusi (ti iṣe Jerusalemu): kẹtẹkẹtẹ meji ti a dì ni gãri wà lọdọ rẹ̀, àle rẹ̀ pẹlu si wà lọdọ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan