Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 18:10 - Bibeli Mimọ

10 Joṣua si ṣẹ́ keké fun wọn ni Ṣilo niwaju OLUWA: nibẹ̀ ni Joṣua si pín ilẹ na fun awọn ọmọ Israeli gẹgẹ bi ipín wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Joṣua bá bá wọn ṣẹ́ gègé ní Ṣilo, níwájú OLUWA, bẹ́ẹ̀ ni Joṣua ṣe pín ilẹ̀ fún àwọn ọmọ Israẹli. Ó fún ẹ̀yà kọ̀ọ̀kan ní ìpín tirẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Joṣua sì ṣẹ́ gègé fún wọn ní Ṣilo ní iwájú Olúwa, Joṣua sì pín ilẹ̀ náà fún àwọn Israẹli gẹ́gẹ́ bí ìpín ẹ̀yà wọn ní ibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 18:10
24 Iomraidhean Croise  

Bayi li a fi iṣẹkeké pin wọn, iru kan mọ ikeji pẹlu; nitori awọn olori ibi mimọ́, ati olori ti Ọlọrun wà ninu awọn ọmọ Eleasari, ati ninu awọn ọmọ Itamari.


AWỌN olori awọn enia si ngbe Jerusalemu: awọn enia iyokù si dìbo lati mu ẹnikan ninu ẹnimẹwa lati ma gbe Jerusalemu, ilu mimọ́, ati mẹsan iyokù lati ma gbe ilu miran.


On ni yio yàn ilẹ-ini wa fun wa, ọlá Jakobu, ẹniti o fẹ.


Nitoripe iwọ, Ọlọrun, li o ti gbọ́ ẹjẹ́ mi: iwọ ti fi ogún awọn ti o bẹ̀ru orukọ rẹ fun mi.


Keké mu ìja pari, a si làja lãrin awọn alagbara.


Ẹ si lọ nisisiyi, si ibujoko mi, ti o wà ni Ṣilo, ni ibi ti emi fi orukọ mi si li àtetekọṣe, ki ẹ si ri ohun ti emi ṣe si i nitori ìwa-buburu enia mi, Israeli.


Yio si ṣe pe, ìbo ni ẹ o fi pin i ni ogún fun ara nyin, ati fun awọn alejo ti o ṣe atipo lãrin nyin, ti nwọn bi ọmọ lãrin nyin: nwọn o si ri si nyin bi ibilẹ ninu awọn ọmọ Israeli; nwọn o ba nyin pin i li ogún lãrin awọn ẹ̀ya Israeli.


Eyi ni ilẹ ti ẹnyin o fi ìbo pin ni ogún fun awọn ẹ̀ya Israeli, wọnyi si ni ipin wọn, ni Oluwa Ọlọrun wi.


Nitorina iwọ kì yio ni ẹnikan ti yio ta okùn nipa ìbo ninu ijọ enia Oluwa.


OLUWA si sọ fun Mose pe,


Nigbati nwọn si kàn a mọ agbelebu, nwọn pín aṣọ rẹ̀, nwọn si ṣẹ gègé le e: ki eyi ti wolĩ wi ba le ṣẹ, pe, Nwọn pín aṣọ mi fun ara wọn aṣọ ileke mi ni nwọn ṣẹ gègé le.


Gẹgẹ bi iwọ ti fun u li aṣẹ lori enia gbogbo, ki o le fi iye ainipẹkun fun gbogbo awọn ti o fifun u.


Nigbati o si ti run orilẹ-ède meje ni ilẹ Kenaani, o si fi ilẹ wọn fun wọn ni ini fun iwọn ãdọta-le-ni-irinwo ọdun.


Lati là wọn li oju, ki nwọn ki o le yipada kuro ninu òkunkun si imọlẹ, ati kuro lọwọ agbara Satani si Ọlọrun, ki nwọn ki o le gbà idariji ẹ̀ṣẹ, ati ogún pẹlu awọn ti a sọ di mimọ́ nipa igbagbọ ninu mi.


Ki a mã dupẹ lọwọ Baba, ẹniti o mu wa yẹ lati jẹ alabapin ninu ogún awọn enia mimọ́ ninu imọlẹ:


Keké ni nwọn fi ní ilẹ-iní wọn, gẹgẹ bi OLUWA ti palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá, fun awọn ẹ̀ya mẹsan, ati àbọ ẹ̀ya ni.


Gẹgẹ bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose, bẹ̃ni awọn ọmọ Israeli ṣe, nwọn si pín ilẹ na.


Ilẹ ẹ̀ya awọn ọmọ Benjamini yọ jade, gẹgẹ bi idile wọn: àla ipín wọn si yọ si agbedemeji awọn ọmọ Juda ati awọn ọmọ Josefu.


Ẹnyin o si ṣe apejuwe ilẹ na li ọ̀na meje, ẹnyin o si mú apejuwe tọ̀ mi wá nihin, ki emi ki o le ṣẹ́ keké rẹ̀ fun nyin nihin niwaju OLUWA Ọlọrun wa.


Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo.


Awọn ọkunrin na si lọ, nwọn si là ilẹ na já, nwọn si ṣe apejuwe rẹ̀ sinu iwé ni ilu ilu li ọ̀na meje, nwọn si pada tọ̀ Joṣua wá, si ibudó ni Ṣilo.


Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.


Wò o, emi ti pín awọn orilẹ-ède wọnyi ti o kù fun nyin, ni ilẹ-iní fun awọn ẹ̀ya nyin, lati Jordani lọ, pẹlu gbogbo awọn orilẹ-ède ti mo ti ke kuro, ani titi dé okun nla ni ìha ìwọ-õrùn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan