Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 18:1 - Bibeli Mimọ

1 GBOGBO ijọ awọn ọmọ Israeli si pejọ ni Ṣilo, nwọn si gbé agọ́ ajọ ró nibẹ̀: a si ṣẹgun ilẹ na niwaju wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Israẹli ti ṣẹgun ilẹ̀ náà, gbogbo wọn péjọ sí Ṣilo, wọ́n sì pa àgọ́ àjọ níbẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli péjọ ní Ṣilo, wọ́n si kọ́ àgọ́ ìpàdé ní ibẹ̀. Gbogbo ilẹ̀ náà sì wà ní abẹ́ àkóso wọn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 18:1
26 Iomraidhean Croise  

Nitoripe, emi ko iti gbe inu ile kan lati ọjọ ti emi ti mu awọn ọmọ Israeli goke ti ilẹ Egipti wá, titi di oni yi, ṣugbọn emi ti nrin ninu agọ, ati ninu agberin.


Jeroboamu si wi fun aya rẹ̀ pe, Dide, emi bẹ̀ ọ, si pa ara rẹ dà, ki a má ba le mọ̀ ọ li aya Jeroboamu; ki o si lọ si Ṣilo: kiyesi i, nibẹ li Ahijah, woli wà, ti o sọ fun mi pe, emi o jọba lori enia yi.


Aya Jeroboamu si ṣe bẹ̃, o si dide, o si lọ si Ṣilo, o si wá si ile Ahijah. Ṣugbọn Ahijah kò riran; nitoriti oju rẹ̀ fọ́ nitori ogbó rẹ̀.


Solomoni si le Abiatari kuro ninu iṣẹ alufa Oluwa; ki o le mu ọ̀rọ Oluwa ṣẹ, ti o ti sọ nipa ile Eli ni Ṣilo.


Bẹ̃li awọn ọmọ na wọ inu rẹ̀ lọ, nwọn si gbà ilẹ na, iwọ si tẹ ori awọn ara ilẹ na ba niwaju wọn, awọn ara Kenaani, o si fi wọn le ọwọ wọn, pẹlu ọba wọn, ati awọn enia ilẹ na, ki nwọn ki o le fi wọn ṣe bi o ti wù wọn.


Bẹ̃li o kọ̀ agọ Ṣilo silẹ, agọ ti o pa ninu awọn enia.


O si kọlu awọn ọta rẹ̀ lẹhin; o sọ wọn di ẹ̀gan titi aiye.


Emi o si ṣe ile yi bi Ṣilo, emi o si ṣe ilu yi ni ifibu si gbogbo orilẹ-ède aiye.


Ẽṣe ti iwọ sọ asọtẹlẹ li orukọ Oluwa wipe, Ile yi yio dabi Ṣilo, ati ilu yi yio di ahoro laini olugbe? Gbogbo enia kojọ pọ̀ tì Jeremiah ni ile Oluwa.


Nigbana ni ọgọrin ọkunrin wá lati Ṣekemu, lati Ṣilo, ati lati Samaria, ti nwọn fá irungbọn wọn, nwọn fà aṣọ wọn ya, nwọn si ṣá ara wọn lọgbẹ, nwọn mu ọrẹ-ẹbọ ati turari li ọwọ wọn lati mu u wá si ile Oluwa.


Ti a o si fi ṣẹ́ ilẹ na niwaju OLUWA: lẹhin na li ẹnyin o pada, ẹnyin o si jẹ́ àlailẹṣẹ niwaju OLUWA, ati niwaju Israeli; ilẹ yi yio si ma jẹ́ iní nyin niwaju OLUWA.


Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi;


Ẹ̀ya meje si kù ninu awọn ọmọ Israeli, ti kò ti igbà ilẹ-iní wọn.


Awọn ọkunrin na si dide, nwọn si lọ: Joṣua si paṣẹ fun awọn ti o lọ ṣe apejuwe ilẹ na, wipe, Ẹ lọ, ki ẹ si rìn ilẹ na já, ki ẹ si ṣe apejuwe rẹ̀, ki ẹ si pada tọ̀ mi wá, ki emi ki o le ṣẹ́ keké fun nyin niwaju OLUWA ni Ṣilo.


Wọnyi ni ilẹ-iní ti Eleasari alufa, ati Joṣua ọmọ Nuni, ati awọn olori awọn baba ẹ̀ya awọn ọmọ Israeli fi keké pín ni ilẹ-iní ni Ṣilo niwaju OLUWA li ẹnu-ọ̀na agọ ajọ. Bẹ̃ni nwọn pari pipín ilẹ na.


Nwọn si wi fun wọn ni Ṣilo ni ilẹ Kenaani pe, OLUWA palaṣẹ lati ọwọ́ Mose wá lati fun wa ni ilu lati ma gbé, ati àgbegbe wọn fun ohun-ọ̀sin wa.


Nigbati awọn ọmọ Israeli gbọ́ ọ, gbogbo ijọ awọn ọmọ Israeli kó ara wọn jọ ni Ṣilo, lati gòke lọ ibá wọn jagun.


Njẹ bi o ba ṣepe ilẹ iní nyin kò ba mọ́, ẹ rekọja si ilẹ iní OLUWA, nibiti agọ́ OLUWA ngbé, ki ẹ si gbà ilẹ-iní lãrin wa: ṣugbọn ẹnyin má ṣe ṣọ̀tẹ si OLUWA, bẹ̃ni ki ẹ má ṣe ṣọ̀tẹ si wa, ni mimọ pẹpẹ miran fun ara nyin lẹhin pẹpẹ OLUWA Ọlọrun wa.


Awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi, ati àbọ ẹ̀ya Manasse si pada, nwọn si lọ kuro lọdọ awọn ọmọ Israeli lati Ṣilo, ti mbẹ ni ilẹ Kenaani, lati lọ si ilẹ Gileadi, si ilẹ iní wọn, eyiti nwọn ti gbà, gẹgẹ bi aṣẹ OLUWA lati ọwọ́ Mose wá.


Nwọn si gbé ere fifin ti Mika ṣe kalẹ ni gbogbo ọjọ́ ti ile Ọlọrun fi wà ni Ṣilo.


Nwọn si ri irinwo wundia ninu awọn ara Jabeṣi-gileadi, ti kò ti imọ̀ ọkunrin nipa ibadapọ̀: nwọn si mú wọn wá si ibudó ni Ṣilo, ti o wà ni ilẹ Kenaani.


Nwọn si wipe, Kiyesi i, ajọ OLUWA wà li ọdọdún ni Ṣilo ni ìha ariwa Beti-eli, ni ìha ìla-õrùn ti opópo ti o lọ soke lati Beti-eli lọ titi dé Ṣekemu, ati ni ìha gusù ti Lebona.


Nigbati o si gba ọmu li ẹnu rẹ̀, o si mu u goke lọ pẹlu ara rẹ̀, pẹlu ẹgbọrọ malu mẹta, ati iyẹfun efa kan, ati igo ọti-wain kan, o si mu u wá si ile Oluwa ni Ṣilo: ọmọ na si wà li ọmọde.


Ọkunrin yi a ma ti ilu rẹ̀ lọ lọdọdun lati sìn ati lati ṣe irubọ si Oluwa awọn ọmọ-ogun ni Ṣilo. Ọmọ Eli mejeji Hofni ati Finehasi alufa Oluwa, si wà nibẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan