Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 17:2 - Bibeli Mimọ

2 Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Wọ́n fún àwọn ìdílé Manase yòókù ní ilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn: àwọn bíi Abieseri, Heleki, Asirieli, Ṣekemu, Heferi, ati Ṣemida. Àwọn ni ọmọkunrin Manase, tíí ṣe ọmọ Josẹfu; wọ́n sì jẹ́ olórí fún àwọn ìdílé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Nítorí náà ìpín yìí wà fún ìyókù àwọn ènìyàn Manase: ní agbo ilé Abieseri, Heleki, Asrieli, Ṣekemu, Heferi àti Ṣemida. Ìwọ̀nyí ní àwọn ọmọ ọkùnrin Manase ọmọ Josẹfu ní agbo ilé wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 17:2
6 Iomraidhean Croise  

Arabinrin rẹ̀, Hammoleketi, bi Iṣodi, ati Abieseri, ati Mahala.


EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani.


Ṣugbọn Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, kò ní ọmọkunrin, bikoṣe ọmọbinrin: awọn wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀, Mala, ati Noa, Hogla, Milka, ati Tirsa.


Angeli OLUWA kan si wá, o si joko labẹ igi-oaku kan ti o wà ni Ofra, ti iṣe ti Joaṣi ọmọ Abieseri: Gideoni ọmọ rẹ̀ si npakà nibi ifọnti, lati fi i pamọ́ kuro loju awọn Midiani.


On si wi fun wọn pe, Kini mo ha ṣe nisisiyi ti a le fiwe ti nyin? Ẽṣẹ́ àjara Efraimu kò ha san jù ikore-àjara Abieseri lọ?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan