Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 17:1 - Bibeli Mimọ

1 EYI si ni ipín ẹ̀ya Manasse; nitori on li akọ́bi Josefu. Bi o ṣe ti Makiri akọ́bi Manasse, baba Gileadi, nitori on ṣe ologun, nitorina li o ṣe ní Gileadi ati Baṣani.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Wọ́n pín ilẹ̀ fún ẹ̀yà Manase nítorí pé ó jẹ́ àkọ́bí Josẹfu. Makiri, baba Gileadi, tí ó jẹ́ àkọ́bí Manase ni wọ́n fún ní ilẹ̀ Gileadi ati Baṣani nítorí pé ó jẹ́ akọni ati akikanju eniyan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Èyí ní ìpín ẹ̀yà Manase tí í ṣe àkọ́bí Josẹfu, fún Makiri, àkọ́bí Manase. Makiri sì ni baba ńlá àwọn ọmọ Gileadi, tí ó ti gba Gileadi àti Baṣani nítorí pé àwọn ọmọ Makiri jẹ́ jagunjagun ńlá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 17:1
20 Iomraidhean Croise  

Josefu si sọ orukọ akọ́bi ni Manasse: wipe, Nitori ti Ọlọrun mu mi gbagbe gbogbo iṣẹ́ mi, ati gbogbo ile baba mi.


Orukọ ekeji li o si sọ ni Efraimu: nitori Ọlọrun ti mu mi bisi i ni ilẹ ipọnju mi.


Manasse ati Efraimu li a si bí fun Josefu ni ilẹ Egipti, ti Asenati ọmọbinrin Potifera alufa Oni bí fun u.


Nigbati Josefu ri pe baba rẹ̀ fi ọwọ́ ọtún rẹ̀ lé Efraimu lori, inu rẹ̀ kò dùn: o si mú baba rẹ̀ li ọwọ́, lati ṣí i kuro li ori Efraimu si ori Manasse.


Josefu si wi fun baba rẹ̀ pe, Bẹ̃kọ, baba mi: nitori eyi li akọ́bi; fi ọwọ́ ọtún rẹ lé e li ori.


Josefu si ri awọn ọmọloju Efraimu ti iran kẹta; awọn ọmọ Makiri, ọmọ Manasse li a si gbé kà ori ẽkun Josefu pẹlu.


On si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn ọmọ Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli.


Ṣugbọn Geṣuri, ati Aramu, gbà ilu Jairi lọwọ wọn, pẹlu Kenati, ati ilu rẹ̀: ani ọgọta ilu. Gbogbo wọnyi ni awọn ọmọ Makiri baba Gileadi.


Bayi li Oluwa Ọlọrun wi; eyi ni yio jẹ ãlà, ti ẹnyin o fi jogún ilẹ na fun ara nyin fun ẹ̀ya mejila Israeli: Josefu yio ni ipin meji.


Ati ni àgbegbe Naftali, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Manasse.


Awọn ọmọ Manasse: ti Makiri, idile Makiri: Makiri si bi Gileadi: ti Gileadi, idile awọn ọmọ Gileadi.


NIGBANA ni awọn ọmọbinrin Selofehadi, ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manasse, ti idile Manasse ọmọ Josefu wá: wọnyi si li orukọ awọn ọmọbinrin rẹ̀; Mala, Noa, ati Hogla, ati Milka, ati Tirsa.


Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká.


Ṣugbọn ki o jẹwọ ọmọ obinrin ti o korira li akọ́bi, ni fifi ipín meji fun u ninu ohun gbogbo ti o ní: nitoripe on ni ipilẹṣẹ agbara rẹ̀; itọsi akọ́bi ni tirẹ̀.


Awọn ọmọ Manasse iyokù si ní ilẹ-iní gẹgẹ bi idile wọn; awọn ọmọ Abieseri, ati awọn ọmọ Heleki, ati awọn ọmọ Asrieli, ati awọn ọmọ Ṣekemu, ati awọn ọmọ Heferi, ati awọn ọmọ Ṣemida: awọn wọnyi ni awọn ọmọ Manasse ọmọ Josefu gẹgẹ bi idile wọn.


Njẹ fun àbọ ẹ̀ya Manasse ni Mose ti fi ilẹ-iní wọn fun ni Baṣani: ṣugbọn fun àbọ ẹ̀ya ti o kù ni Joṣua fi ilẹ-iní fun pẹlu awọn arakunrin wọn ni ìha ihin Jordani ni ìwọ-õrùn. Nigbati Joṣua si rán wọn pada lọ sinu agọ́ wọn, o sure fun wọn pẹlu,


Lati Efraimu ni nwọn ti wá awọn ti gbongbo wọn wà ni Amaleki; lẹhin rẹ, Benjamini, lãrin awọn enia rẹ; lati Makiri ni awọn alaṣẹ ti sọkalẹ wá, ati lati Sebuluni li awọn ẹniti nmú ọ̀pá-oyè lọwọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan