Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:5 - Bibeli Mimọ

5 Àla awọn ọmọ Efraimu gẹgẹ bi idile wọn li eyi: ani àla ilẹ-iní wọn ni ìha ìla-õrùn ni Atarotu-adari, dé Beti-horoni òke;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

5 Èyí ni ilẹ̀ tí àwọn ọmọ Efuraimu gbà, gẹ́gẹ́ bí iye ìdílé wọn. Ààlà ilẹ̀ wọn ní apá ìlà oòrùn bẹ̀rẹ̀ láti Atarotu Adari, títí dé apá òkè Beti Horoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

5 Èyí ni ilẹ̀ Efraimu, ní agbo ilé agbo ilé: Ààlà ìní wọn lọ láti Atarotu-Addari ní ìlà-oòrùn lọ sí Òkè Beti-Horoni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:5
7 Iomraidhean Croise  

On si fi i jọba lori Gileadi, ati lori awọn ọmọ Aṣuri, ati lori Jesreeli, ati lori Efraimu, ati lori Benjamini, ati lori gbogbo Israeli.


Ọmọ rẹ̀ obinrin ni Sera, ẹniti o tẹ̀ Bet-horoni dó, ti isalẹ ati ti òke, ati Usseni Ṣera.


Ati awọn ini ati ibugbe wọn ni Beteli, ati ilu rẹ̀, ati niha ìla-õrùn Naarani, niha ìwọ-õrùn Geseri pẹlu ilu rẹ̀: Ṣekemu pẹlu ati ilu rẹ̀, titi de Gasa ilu rẹ̀:


Ati ni àgbegbe Manasse, lati ihà ila-õrun, de ihà iwọ-õrun, ipin kan, fun Efraimu.


OLUWA si fọ́ wọn niwaju Israeli, o si pa wọn ni ipakupa ni Gibeoni, o si lepa wọn li ọ̀na òke Beti-horoni, o si pa wọn dé Aseka, ati dé Makkeda.


O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu;


Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan