Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 16:2 - Bibeli Mimọ

2 O si ti Beti-eli yọ si Lusi, o si kọja lọ si àgbegbe Arki dé Atarotu;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Láti Bẹtẹli, ó lọ sí Lusi, ó sì kọjá lọ sí Atarotu, níbi tí àwọn ọmọ Ariki ń gbé.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ó sì tẹ̀síwájú láti Beteli (tí í ṣe Lusi) kọjá lọ sí agbègbè àwọn ará Arki ní Atarotu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 16:2
8 Iomraidhean Croise  

O si pè orukọ ibẹ̀ na ni Beteli: ṣugbọn Lusi li orukọ ilu na ri.


O si ṣe, Dafidi de ori oke, nibiti o gbe wolẹ̀ sin Ọlọrun, si wõ, Huṣai ara Arki nì si wá lati pade rẹ̀ ti on ti aṣọ rẹ̀ yiya, ati erupẹ, li ori rẹ̀.


Huṣai ọrẹ Dafidi si wá si ilu, Absalomu si wá si Jerusalemu.


O si ṣe, nigbati Huṣai ará Arki, ọrẹ Dafidi tọ Absalomu wá, Huṣai si wi fun Absalomu pe, Ki ọba ki o pẹ, ki ọba ki o pẹ.


Ahitofeli si jẹ ìgbimọ ọba: ati Huṣai ara Arki ni ọrẹ ọba.


Ati awọn ini ati ibugbe wọn ni Beteli, ati ilu rẹ̀, ati niha ìla-õrùn Naarani, niha ìwọ-õrùn Geseri pẹlu ilu rẹ̀: Ṣekemu pẹlu ati ilu rẹ̀, titi de Gasa ilu rẹ̀:


Àla na si ti ibẹ̀ lọ si Lusi, si ìha Lusi (ti ṣe Beti-eli), ni ìha gusù; àla na si sọkale lọ si Atarotu-adari, lẹba òke ti mbẹ ni gusù Beti-horoni isalẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan