Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:9 - Bibeli Mimọ

9 A si fà àla na lati ori òke lọ si isun omi Neftoa, o si nà lọ si ilu òke Efroni; a si fà àla na lọ si Baala, (ti iṣe Kirjati-jearimu:)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 Láti ibẹ̀, ó tún bẹ̀rẹ̀ láti orí òkè títí dé odò Nefitoa, ó lọ sí apá ibi tí àwọn ìlú ńláńlá wà lẹ́bàá òkè Efuroni, ó wá pada sí apá Baala (tí a tún ń pè ní Kiriati Jearimu.)

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ààlà náà sì lọ láti orí òkè lọ sí ìsun omi Nefitoa, ó sì jáde sí ìlú Òkè Efroni, ó sì lọ sí apá ìsàlẹ̀ Baalahi, (tí í ṣe, Kiriati-Jearimu).

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:9
8 Iomraidhean Croise  

Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu.


Dafidi si gòke ati gbogbo Israeli si Baala, si Kirjat-jearimu, ti iṣe ti Juda, lati mu apoti ẹ̀ri Ọlọrun Oluwa gòke lati ibẹ wá, ti ngbe arin Kerubimu, nibiti a npe orukọ Ọlọrun.


Baala, ati Iimu, ati Esemu;


Kiriati-baali (ti iṣe Kiriati-jearimu), ati Rabba; ilu meji pẹlu ileto wọn.


Ati apa gusù ni lati ipẹkun Kiriati-jearimu, àla na si yọ ìwọ-õrùn, o si yọ si isun omi Neftoa:


Awọn ọmọ Israeli si dide, nwọn si dé ilu wọn ni ijọ́ kẹta. Njẹ ilu wọn ni Gibeoni, ati Kefira, ati Beerotu, ati Kiriati-jearimu.


Nwọn si gòke lọ, nwọn si dó si Kiriati-jearimu, ni Juda: nitorina ni nwọn ṣe npè ibẹ̀ na ni Mahane-dani titi o fi di oni yi: kiyesi i, o wà lẹhin Kiriati-jearimu.


Nwọn ran awọn onṣẹ si awọn ara Kirjatjearimu wipe, Awọn Filistini mu apoti Oluwa wá; ẹ sọkalẹ wá, ki ẹ gbe e lọ sọdọ nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan