Joṣua 15:7 - Bibeli Mimọ7 Àla na si gòke lọ si Debiri lati afonifoji Akoru, ati bẹ̃ lọ si ìha ariwa, ti o dojukọ Gilgali, ti mbẹ niwaju òke Adummimu, ti mbẹ ni ìha gusù odò na: àla si kọja si apa omi Eni-ṣemeṣi, o si yọ si Eni-rogeli: Faic an caibideilYoruba Bible7 Ó lọ láti àfonífojì Akori títí dé Debiri, ó wá yípo lọ sí apá ìhà àríwá, lọ sí Giligali, tí ó dojú kọ gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ Adumimu, tí ó wà ní apá gúsù àfonífojì náà. Lẹ́yìn náà, ó lọ sí ibi odò Enṣemeṣi, ó sì pin sí Enrogeli. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní7 Ààlà náà gòkè lọ títí dé Debiri láti Àfonífojì Akori, ó sì yípadà sí àríwá Gilgali, èyí tí ń bẹ ní iwájú òkè Adummimu, tí ń bẹ ní ìhà gúúsù odò náà. Ó sì tẹ̀síwájú sí apá omi En-Ṣemeṣi, ó sì jáde sí En-Rogeli. Faic an caibideil |