Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:4 - Bibeli Mimọ

4 Lati ibẹ̀ o lọ dé Asmoni, o si nà lọ si odò Egipti; opín ilẹ na si yọ si okun: eyi ni yio jẹ́ àla ni gusù nyin.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Lẹ́yìn náà, ó lọ títí dé Asimoni, ó tọ ipa odò Ijipti, ó sì pin sí Òkun Mẹditarenia. Òun ni yóo jẹ́ ààlà ilẹ̀ Juda ní apá ìhà gúsù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Ó tún kọjá lọ sí Asmoni, ó sì papọ̀ mọ́ Wadi ti Ejibiti, ó parí sí Òkun. Èyí ni ààlà wọn ní ìhà gúúsù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:4
8 Iomraidhean Croise  

Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate:


Ati li àkoko na, Solomoni papejọ kan, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ajọ nla-nlã ni, lati iwọ Hamati titi de odò Egipti, niwaju Oluwa Ọlọrun wa, ijọ meje on ijọ meje, ani ijọ mẹrinla.


Emi o si fi opinlẹ rẹ lelẹ, lati Okun Pupa wá titi yio fi dé okun awọn ara Filistia, ati lati aṣalẹ̀ nì wá dé odò nì; nitoriti emi o fi awọn olugbe ilẹ na lé nyin lọwọ; iwọ o si lé wọn jade kuro niwaju rẹ.


Yio si ṣe li ọjọ na, Oluwa yio ja eso kuro ni ibu odò si iṣàn Egipti, a o si ṣà nyin jọ li ọkọkan, ẹnyin ọmọ Israeli.


Ki opinlẹ rẹ̀ ki o si yiká lati Asmoni lọ dé odò Egipti, okun ni yio si jẹ́ opin rẹ̀.


Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù:


O si lọ si apa gusù òke Akrabbimu, o si lọ si Sini, o si gòke lọ ni ìha gusù Kadeṣi-barnea, o si lọ ni ìha Hesroni, o si gòke lọ si Adari, o si yiká lọ dé Karka:


Aṣdodu, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; Gasa, pẹlu ilu rẹ̀ ati ileto rẹ̀; dé odò Egipti, ati okun nla, ati àgbegbe rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan