Joṣua 15:11 - Bibeli Mimọ11 Àla na si kọja lọ si ẹba Ekroni si ìha ariwa: a si fà àla na lọ dé Ṣikroni, o si kọja lọ si òke Baala, o si yọ si Jabneeli; àla na si yọ si okun. Faic an caibideilYoruba Bible11 Ó tún gba ti àwọn òkè tí ó wà ní ìhà àríwá Ekironi, ó wá yípo lọ sí Ṣikeroni. Lẹ́yìn náà, ó kọjá lọ sí òkè Baala títí dé Jabineeli, ó wá lọ parí sí Òkun Mẹditarenia. Faic an caibideilBíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní11 Ààlà náà sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Ekroni, ó sì yípadà lọ sí Ṣikkeroni, ó sì yípadà lọ sí Òkè Baalahi, ó sì dé Jabneeli, ààlà náà sì parí sí Òkun. Faic an caibideil |
Nwọn si wi fun u pe, Ọkunrin kan li o gòke lati pade wa, o si wi fun wa pe, Ẹ lọ, ẹ pada tọ̀ ọba ti o rán nyin, ki ẹ si wi fun u pe, Bayi li Oluwa wi, kò ṣepe nitoriti kò si Ọlọrun ni Israeli, ni iwọ fi ranṣẹ lọ ibère lọwọ Baalsebubu oriṣa Ekroni? nitorina, iwọ kì o sọ̀kalẹ kuro lori akete nì ti iwọ ti gùn, ṣugbọn kikú ni iwọ o kú.