Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 15:10 - Bibeli Mimọ

10 Àla na yi lati Baala lọ si ìha ìwọ-õrùn si òke Seiri, o si kọja lọ si ẹba òke Jearimu (ti ṣe Kesaloni), ni ìha ariwa, o si sọkalẹ lọ si Beti-ṣemeṣi, o si kọja lọ si Timna:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

10 Ààlà náà tún yípo lọ sí ìwọ̀ oòrùn Baala, sí apá òkè Seiri, lọ sí apá ìhà àríwá òkè Jearimu (tí a tún ń pè ní Kesaloni), ó bá tún dà gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ lọ sí Beti Ṣemeṣi títí dé ìkọjá Timna.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

10 Ààlà tí ó yípo láti Baalahi lọ sí ìhà ìwọ̀-oòrùn sí òkè Seiri, ó sì lọ sí gẹ̀rẹ́gẹ̀rẹ́ àríwá òkè Jearimu (tí í ṣe, Kesaloni), ó sì sọ̀kalẹ̀ lọ sí Beti-Ṣemeṣi, ó sì kọjá lọ sí Timna.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 15:10
12 Iomraidhean Croise  

Dafidi si dide, o si lọ, ati gbogbo awọn enia ti mbẹ lọdọ rẹ̀, lati Baale ti Juda wá, lati mu apoti-ẹri Ọlọrun ti ibẹ wá, eyi ti a npè orukọ rẹ̀ ni orukọ Oluwa awọn ọmọ-ogun ti o joko lãrin awọn Kerubu.


Ṣugbọn Amasiah kò fẹ igbọ́. Nitorina Jehoaṣi ọba Israeli gòke lọ; on ati Amasiah ọba Juda si wò ara wọn li oju ni Betṣemeṣi, ti iṣe ti Juda.


Awọn ara Filistia pẹlu ti gbé ogun lọ si ilu pẹtẹlẹ wọnni, ati siha gusu Juda, nwọn si ti gbà Bet-ṣemeṣi, ati Ajaloni, ati Gederoti, ati Ṣoko pẹlu ileto rẹ̀, Timna pẹlu ileto rẹ̀, ati Gimso pẹlu ati ileto rẹ̀: nwọn si ngbe ibẹ.


Àla na si kọja lọ si ẹba Ekroni si ìha ariwa: a si fà àla na lọ dé Ṣikroni, o si kọja lọ si òke Baala, o si yọ si Jabneeli; àla na si yọ si okun.


Kaini, Gibea, ati Timna; ilu mẹwa pẹlu ileto wọn.


Ati Ironi, ati Migdali-eli, Horemu, ati Beti-anati, ati Beti-ṣemeṣi; ilu mọkandilogun pẹlu ileto wọn.


Ati Aini pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Jutta pẹlu àgbegbe rẹ̀, ati Beti-ṣemeṣi pẹlu àgbegbe rẹ̀; ilu mẹsan ninu awọn ẹ̀ya meji wọnni.


SAMSONI si sọkalẹ lọ si Timna, o si ri obinrin kan ni Timna ọkan ninu awọn ọmọbinrin awọn Filistini.


Nigbana ni Samsoni sọkalẹ lọ si Timna, ati baba rẹ̀ ati iya rẹ̀, o si dé ibi ọgbà-àjara ti o wà ni Timna: si kiyesi i, ẹgbọrọ kiniun kan nke ramuramu si i.


Ki ẹ si kiyesi i, bi o ba lọ si ọ̀na agbegbe tirẹ̀ si Betṣemeṣi, a jẹ pe on na li o ṣe wa ni buburu yi: ṣugbọn bi kò ba ṣe bẹ̃, nigbana li awa o to mọ̀ pe, ki iṣe ọwọ́ rẹ̀ li o lù wa, ṣugbọn ẽṣi li o ṣe si wa.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan