Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:9 - Bibeli Mimọ

9 Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji na, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ Medeba titi dé Diboni;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

9 láti Aroeri tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni ati ìlú tí ó wà ní ààrin gbùngbùn àfonífojì náà, ati ilẹ̀ tí ó tẹ́jú ní Medeba títí dé Diboni;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

9 Ó sì lọ títí láti Aroeri tí ń bẹ létí Àfonífojì Arnoni, àti láti ìlú náà tí ń bẹ ní àárín Àfonífojì náà, àti pẹ̀lú gbogbo pẹ̀tẹ́lẹ̀ Medeba títí dé Diboni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:9
15 Iomraidhean Croise  

Nwọn si kọja odo Jordani, nwọn si pagọ ni Aroeri, ni iha apá ọtún ilu ti o wà lagbedemeji afonifoji Gadi, ati si iha Jaseri:


Bẹ̃ni nwọn bẹwẹ ẹgbã mẹrindilogun kẹkẹ́ ati ọba Maaka ati awọn enia rẹ̀; nwọn si wá nwọn si do niwaju Medeba. Awọn ọmọ Ammoni si ko ara wọn jọ lati ilu wọn, nwọn si wá si ogun.


Ati fun ileto, pẹlu oko wọn, ninu awọn ọmọ Juda ngbe Kirjat-arba, ati ileto rẹ̀, ati ni Diboni, ati ileto rẹ̀, ati ni Jekabseeli, ati ileto rẹ̀,


On ti goke lọ si Bajiti, ati si Diboni, ibi giga wọnni, lati sọkun: Moabu yio hu lori Nebo, ati lori Medeba: gbogbo ori wọn ni yio pá, irungbọ̀n olukulùku li a o fá.


Iwọ olugbe ọmọbinrin Diboni, sọkalẹ lati inu ogo, ki o si ma gbe ibi ongbẹ; nitori afiniṣe-ijẹ. Moabu yio goke wá sori rẹ, yio si pa ilu olodi rẹ run.


Ati sori Diboni, ati sori Nebo, ati sori Bet-diblataimu.


Awọn oluparun yio wá sori olukuluku ilu, ilu kan kì o si bọ́: afonifoji pẹlu yio ṣegbe, a o si pa pẹtẹlẹ run, gẹgẹ bi Oluwa ti wi.


Awa tafà si wọn; Heṣboni ṣegbé titi dé Diboni, awa si ti run wọn titi dé Nofa, ti o dé Medeba.


Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati lati ilu ni lọ ti mbẹ lẹba afonifoji nì, ani dé Gileadi, kò sí ilu kan ti o le jù fun wa: OLUWA Ọlọrun wa fi gbogbo wọn fun wa:


Ati ilẹ na yi, ti awa gbà ni ìgbana, lati Aroeri, ti mbẹ lẹba afonifoji Arnoni, ati àbọ òke Gileadi, ati ilu inu rẹ̀, ni mo fi fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun awọn ọmọ Gadi:


Ati awọn ọmọ Reubeni, ati awọn ọmọ Gadi ni mo fi fun lati Gileadi, ani dé afonifoji Arnoni, agbedemeji afonifoji, ati opinlẹ rẹ̀; ani dé odò Jaboku, ti iṣe ipinlẹ awọn ọmọ Ammoni;


Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni;


Ati gbogbo ilu Sihoni ọba awọn Amori, ti o jọba ni Heṣboni, titi dé àgbegbe awọn ọmọ Ammoni:


Àla wọn bẹ̀rẹ lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ati ilu ti mbẹ lãrin afonifoji nì, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ti mbẹ ni ìha Medeba;


Pẹlu rẹ̀ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ti gbà ilẹ-iní wọn, ti Mose fi fun wọn ni ìha keji Jordani ni ìha ìla õrùn, bi Mose iranṣẹ OLUWA ti fi fun wọn;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan