Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:3 - Bibeli Mimọ

3 Lati Ṣihori, ti mbẹ niwaju Egipti, ani titi dé àgbegbe Ekroni ni ìha ariwa, ti a kà kún awọn ara Kenaani: awọn ijoye Filistia marun; awọn ara Gasa, ati awọn ara Aṣdodi, awọn ara Aṣkeloni, awọn Gitti, ati awọn ara Ekroni; awọn Affimu pẹlu ni gusù:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 láti odò Ṣihori, ní apá ìlà oòrùn ilẹ̀ Ijipti, títí lọ sí apá àríwá ní ààlà Ekironi tí ó jẹ́ ti àwọn ará Kenaani, (Marun-un ni ọba àwọn ará Filistia, àwọn nìwọ̀nyí: ọba Gasa, ti Aṣidodu, ti Aṣikeloni, ti Gati, ati ti Ekironi) ati ilẹ̀ àwọn Afimu ní ìhà gúsù.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 láti odò Ṣihori ní ìlà-oòrùn Ejibiti sí agbègbè Ekroni ìhà àríwá, gbogbo rẹ̀ ni a kà kún Kenaani (agbègbè ìjòyè Filistini márùn-ún ní Gasa, Aṣdodu, Aṣkeloni, Gitti àti Ekroni; ti àwọn ará Affimu);

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:3
18 Iomraidhean Croise  

Ati awọn ọmọ Hamu; Kuṣi, ati Misraimu, ati Futi, ati Kenaani.


Li ọjọ́ na gan li OLUWA bá Abramu dá majẹmu pe, irú-ọmọ rẹ ni mo fi ilẹ yi fun, lati odò Egipti wá, titi o fi de odò nla nì, odò Euferate:


Ati li àkoko na, Solomoni papejọ kan, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, ajọ nla-nlã ni, lati iwọ Hamati titi de odò Egipti, niwaju Oluwa Ọlọrun wa, ijọ meje on ijọ meje, ani ijọ mẹrinla.


Bẹ̃ni Dafidi ko gbogbo Israeli jọ lati odò Egipti ani titi de Hemati, lati mu apoti ẹri Ọlọrun lati Kirjat-jearimu wá.


Ati nipa omi nla iru Sihori, ikorè odò, ni owo ọdun rẹ̀; on ni ọjà awọn orilẹ-ède.


Njẹ nisisiyi kíni iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Egipti, lati mu omi Sihori? tabi kini iwọ ni iṣe ni ipa-ọ̀na Assiria lati mu omi odò rẹ̀.


Ati awọn ọmọ Affimu ti ngbé awọn ileto, titi dé Gasa, awọn ọmọ Kaftori, ti o ti ọdọ Kaftori wá, run wọn, nwọn si ngbé ibẹ̀ ni ipò wọn.)


Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli kò lé awọn Geṣuri, tabi awọn Maakati jade: ṣugbọn awọn Geṣuri ati awọn Maakati ngbé ãrin awọn ọmọ Israeli titi di oni.


Awọn ijoye Filistini tọ̀ ọ wá, nwọn si wi fun u pe, Tàn a, ki o si mọ̀ ibiti agbara nla rẹ̀ gbé wà, ati bi awa o ti ṣe le bori rẹ̀, ki awa ki o le dè e lati jẹ ẹ niyà: olukuluku wa yio si fun ọ ni ẹdẹgbẹfa owo fadakà.


Awọn ijoye Filistini marun, ati gbogbo awọn Kenaani, ati awọn ara Sidoni, ati awọn Hifi ti ngbé òke Lebanoni, lati òke Baali-hermoni lọ dé atiwọ̀ Hamati.


AWỌN Filistini si gbe Apoti Ọlọrun, nwọn si mu u lati Ebeneseri wá si Aṣdodu.


Nitorina nwọn rán apoti Ọlọrun lọ si Ekronu. O si ṣe, bi apoti Ọlọrun ti de Ekronu, bẹ̃li awọn enia Ekronu kigbe wipe, nwọn gbe apoti Ọlọrun Israeli tọ̀ ni wá, lati pa wa, ati awọn enia wa.


Nwọn ranṣẹ nitorina, nwọn si pè gbogbo awọn ijoye Filistini sọdọ wọn, nwọn bere pe, Awa o ti ṣe apoti Ọlọrun Israeli si? Nwọn si dahun pe, Ẹ jẹ ki a gbe apoti Ọlọrun Israeli lọ si Gati. Nwọn si gbe apoti Ọlọrun Israeli na lọ sibẹ.


Nwọn wipe, Kini irubọ na ti a o fi fun u? Nwọn si dahun pe, Iyọdi wura marun, ati ẹ̀liri wura marun, gẹgẹ bi iye ijoye Filistini: nitoripe ajakalẹ arùn kanna li o wà li ara gbogbo nyin, ati awọn ijoye nyin.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan