Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:2 - Bibeli Mimọ

2 Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Ilẹ̀ tí ó kù nìwọ̀nyí: gbogbo agbègbè àwọn ará Filistia ati ti Geṣuri;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 “Èyí ni ilẹ̀ tí ó kù: “gbogbo àwọn agbègbè àwọn Filistini, àti ti ara Geṣuri:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:2
15 Iomraidhean Croise  

Ati Patrusimu, ati Kasluhimu (lati ọdọ ẹniti Filistimu ti wá), ati Kaftorimu.


ÌYAN kan si mu ni ilẹ na, lẹhin ìyan ti o tetekọ mu li ọjọ́ Abrahamu. Isaaki si tọ̀ Abimeleki, ọba awọn ara Filistia lọ, si Gerari.


Nitori ti iranṣẹ rẹ ti jẹ'jẹ kan nigbati emi mbẹ ni Geṣuri ni Siria, pe, Bi Oluwa ba mu mi pada wá si Jerusalemu, nitotọ, emi o si sin Oluwa.


Ekeji rẹ̀ si ni Kileabu, ti Abigaili aya Nabali ara Karmeli nì bi fun u; ẹkẹta si ni Absalomu ọmọ ti Maaka ọmọbinrin Talmai ọba Geṣuri bi fun u.


Nitõtọ, ati ki li ẹnyin ni ifi mi ṣe, ẹnyin Tire ati Sidoni, ati gbogbo ẹkùn Palestina? ẹnyin o ha san ẹsan fun mi? bi ẹnyin ba si san ẹsan fun mi, ni kánkan ati ni koyákoyá li emi o san ẹsan nyin padà sori ara nyin.


Egbe ni fun awọn ẹniti ngbe agbègbe okun, orilẹ-ède awọn ara Kereti! ọ̀rọ Oluwa dojukọ nyin; iwọ Kenaani, ilẹ awọn ara Filistia, emi o tilẹ pa ọ run, ti ẹnikan kì yio gbe ibẹ̀ mọ.


Jairi ọmọ Manasse mú gbogbo ilẹ Argobu, dé opinlẹ Geṣuri ati Maakati; o si sọ wọn, ani Baṣan, li orukọ ara rẹ̀, ni Haffotu-jairi titi, di oni.)


O si jọba li òke Hermoni, ati ni Saleka, ati ni gbogbo Baṣani, titi o fi dé àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati àbọ Gileadi, àla Sihoni ọba Heṣboni.


Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka;


Ṣugbọn awọn ọmọ Israeli kò lé awọn Geṣuri, tabi awọn Maakati jade: ṣugbọn awọn Geṣuri ati awọn Maakati ngbé ãrin awọn ọmọ Israeli titi di oni.


NJẸ wọnyi li awọn orilẹ-ède ti OLUWA fisilẹ, lati ma fi wọn dan Israeli wò, ani iye awọn ti kò mọ̀ gbogbo ogun Kenaani;


Dafidi ati awọn ọmọkunrin rẹ̀ si goke lọ, nwọn si gbe ogun ti awọn ara Geṣuri, ati awọn ara Gesra, ati awọn ara Amaleki: awọn wọnyi li o si ti ngbe ni ilẹ, na nigba atijọ, bi iwọ ti nlọ si Ṣuri titi o fi de ilẹ Egipti.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan