Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 13:1 - Bibeli Mimọ

1 JOṢUA si gbó o si pọ̀ li ọjọ́; OLUWA si wi fun u pe, Iwọ gbó, iwọ si pọ̀ li ọjọ́, ilẹ pipọ̀pipọ si kù lati gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Ní àkókò yìí, Joṣua ti di àgbàlagbà, ogbó sì ti dé sí i. OLUWA bá sọ fún un pé, “Ogbó ti dé sí ọ, ṣugbọn ilẹ̀ pupọ ni ó kù láti gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí Joṣua sì darúgbó tí ọjọ́ orí rẹ̀ sì pọ̀ jọjọ, Olúwa sọ fún un pé, “Ìwọ ti darúgbó púpọ̀, bẹ́ẹ̀ ni ilẹ̀ sì kù lọ́pọ̀lọpọ̀ fún yín láti gbà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 13:1
12 Iomraidhean Croise  

Njẹ Abrahamu on Sara gbó, nwọn si pọ̀ li ọjọ́; o si dẹkun ati ma ri fun Sara bi ìwa obinrin.


DAFIDI ọba si di arugbo, ọjọ rẹ̀ si pọ̀; nwọn si fi aṣọ bò o lara, ṣugbọn kò mõru.


Ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ si Jordani, ijadelọ rẹ̀ yio jẹ Okun Iyọ̀: eyi ni yio jẹ́ ilẹ nyin gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀ yiká kiri.


Fi aṣẹ fun awọn ọmọ Israeli, ki o si wi fun wọn pe, Nigbati ẹnyin ba dé ilẹ Kenaani, (eyi ni ilẹ ti yio bọ́ si nyin lọwọ ni iní, ani ilẹ Kenaani gẹgẹ bi àgbegbe rẹ̀,)


Ṣugbọn nwọn kò li ọmọ, nitoriti Elisabeti yàgan, awọn mejeji si di arugbo.


OLUWA Ọlọrun rẹ, on ni yio rekọja ṣaju rẹ, on ni yio si run orilẹ-ède wọnyi kuro niwaju rẹ, iwọ o si gbà wọn: ati Joṣua, on ni yio gòke ṣaju rẹ, bi OLUWA ti wi.


Eyi ni ilẹ ti o kù; gbogbo ilẹ awọn Filistini, ati gbogbo Geṣuri;


Njẹ nisisiyi, kiyesi i, OLUWA da mi si gẹgẹ bi o ti wi, lati ọdún marunlelogoji yi wá, lati ìgba ti OLUWA ti sọ ọ̀rọ yi fun Mose, nigbati Israeli nrìn kiri li aginjù: si kiyesi i nisisiyi, emi di ẹni arundilãdọrun ọdún li oni.


Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin?


OLUWA si sọ fun Joṣua pe,


O si ṣe lẹhin nkan wọnyi, ni Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ OLUWA kú, o jẹ́ ẹni ãdọfa ọdún.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan