Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 12:2 - Bibeli Mimọ

2 Sihoni ọba Amori, ti ngbé Heṣboni, ti o si jọba lati Aroeri, ti mbẹ leti odò Arnoni, ati ilu ti o wà lãrin afonifoji na, ati àbọ Gileadi, ani titi dé odò Jaboku, àgbegbe awọn ọmọ Ammoni;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 Wọ́n ṣẹgun Sihoni, ọba àwọn ará Amori, tí ń gbé ìlú Heṣiboni. Ilẹ̀ ìjọba rẹ̀ bẹ̀rẹ̀ láti Aroeri, tí ó wà ní etí àfonífojì Arinoni, ati láti agbede meji àfonífojì náà, títí dé odò Jaboku, tí í ṣe ààlà ilẹ̀ àwọn ará Amoni, ó jẹ́ ìdajì ilẹ̀ Gileadi;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Sihoni ọba àwọn Amori, tí ó jẹ ọba ní Heṣboni. Ó ṣe àkóso láti Aroeri tí ń bẹ ní etí odò Arnoni, láti ìlú tó wà ní àárín Àfonífojì náà dé Odò Jabbok, èyí tí ó jẹ́ ààlà àwọn ọmọ Ammoni. Pẹ̀lú ìdajì àwọn ará Gileadi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 12:2
12 Iomraidhean Croise  

O si dide li oru na, o si mú awọn aya rẹ̀ mejeji, ati awọn iranṣẹbinrin rẹ̀ mejeji, ati awọn ọmọ rẹ̀ mọkọkanla, o si kọja iwọdò Jabboku.


Ati Bela ọmọ Asasi, ọmọ Ṣema, ọmọ Joeli, ti ngbe Aroeri, ani titi de Nebo ati Baalmeoni:


Pẹlupẹlu iwọ fi ijọba ati orilẹ-ède fun wọn, o si pin wọn si ìha gbogbo, bẹ̃ni nwọn jogun ilẹ Sihoni, ati ilẹ ọba Heṣboni, ati ilẹ Ogu, ọba Baṣani.


Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani, ati gbogbo ijọba Kenaani:


Iwọ olugbe Aroeri! duro lẹba ọ̀na, ki o si wò; bere lọwọ ẹniti nsa, ati ẹniti nsala, wipe, Kili o ṣe?


Lẹhin igbati o pa Sihoni tán ọba awọn ọmọ Amori, ti o ngbé Heṣboni, ati Ogu ọba Baṣani, ti o ngbé Aṣtarotu, ni Edrei:


Ọba awọn ọmọ Ammoni si da awọn onṣẹ Jefta lohùn pe, Nitoriti Israeli ti gbà ilẹ mi, nigbati nwọn gòke ti Egipti wá, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati titi dé Jordani: njẹ́ nisisiyi fi ilẹ wọnni silẹ li alafia.


Nwọn si gbà gbogbo àgbegbe awọn Amori, lati Arnoni titi dé Jaboku, ati lati aginjù titi dé Jordani.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan