Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 12:1 - Bibeli Mimọ

1 NJẸ wọnyi ni awọn ọba ilẹ na, ti awọn ọmọ Israeli pa, ti nwọn si gbà ilẹ wọn li apa keji Jordani, ni ìha ìla-õrùn, lati odò Arnoni lọ titi dé òke Hermoni, ati gbogbo pẹtẹlẹ̀ ni ìha ìla-õrun:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Àwọn ọmọ Israẹli ṣẹgun àwọn ọba wọnyi, wọ́n sì gba gbogbo ilẹ̀ wọn tí ó wà ní apá ìlà oòrùn, ní òdìkejì odò Jọdani, láti àfonífojì Arinoni títí dé òkè Herimoni, pẹlu gbogbo agbègbè Araba ní apá ìlà oòrùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ìwọ̀nyí ní àwọn ọba ilẹ̀ náà tí àwọn ará Israẹli ṣẹ́gun, tí wọ́n sì gba ilẹ̀ wọn ní ìlà-oòrùn Jordani, láti odò Arnoni dé Òkè Hermoni, pẹ̀lú gbogbo ìhà ìlà-oòrùn aginjù:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 12:1
24 Iomraidhean Croise  

Geberi, ọmọ Uri wà ni ilẹ Gileadi ni ilẹ Sihoni, ọba awọn ara Amori, ati Ogu, ọba Baṣani: ijoye kan li o si wà ni ilẹ na.


Bi ìri Hermoni ti o ṣàn sori òke Sioni: nitori nibẹ ni Oluwa gbe paṣẹ ibukún, ani ìye lailai.


O si fi ilẹ wọn funni ni ini, nitori ti ãnu rẹ̀ duro lailai.


Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ.


Yio si ṣe, bi alarinkiri ẹiyẹ ti a le jade kuro ninu itẹ́-ẹiyẹ, bẹ̃ni ọmọbinrin Moabu yio ri ni iwọdò Arnoni.


Lati ibẹ̀ lọ nwọn ṣí, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ti mbẹ li aginjù, ti o ti àgbegbe awọn ọmọ Amori wá: nitoripe Arnoni ni ipinlẹ Moabu, lãrin Moabu ati awọn Amori.


Israeli si rán onṣẹ si Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, wipe,


Israeli si fi oju idà kọlù u, o si gbà ilẹ rẹ̀ lati Arnoni lọ dé Jaboku, ani dé ti awọn ọmọ Ammoni; nitoripe ipinlẹ ti awọn ọmọ Ammoni lí agbara.


Nitoripe awa ki yio ní ilẹ-iní pẹlu wọn ni ìha ọhún Jordani, tabi niwaju: nitoriti awa ní ilẹ-iní wa ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla õrùn.


Awa o gòke lọ ni ihamọra niwaju OLUWA si ilẹ Kenaani, ki iní wa ni ìha ihin Jordani ki o le jẹ́ ti wa.


Mose si fi ilẹ-ọba Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ati ilẹ-ọba Ogu ọba Baṣani fun wọn, ani fun awọn ọmọ Gadi, ati fun awọn ọmọ Reubeni, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse ọmọ Josefu, ilẹ na, pẹlu ilu rẹ̀ li àgbegbe rẹ̀, ani ilu ilẹ na yiká.


Ẹ dide, ẹ mú ọ̀na nyin pọ̀n, ki ẹ si gòke odò Arnoni: wò o, emi fi Sihoni ọmọ Amori, ọba Heṣboni lé ọ lọwọ, ati ilẹ rẹ̀: bẹ̀rẹsi gbà a, ki o si bá a jagun.


Nigbana ni Sihoni jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Jahasi.


NIGBANA li awa pada, a si lọ soke li ọ̀na Baṣani: Ogu ọba Baṣani si jade si wa, on ati gbogbo awọn enia rẹ̀, fun ìja ni Edrei.


Eyi li ofin na ti Mose filelẹ niwaju awọn ọmọ Israeli:


Ni ìha ẹ̀bá Jordani, ni afonifoji ti o kọjusi Beti-peori, ni ilẹ Sihoni ọba awọn ọmọ Amori, ti ngbé Heṣboni, ẹniti Mose ati awọn ọmọ Israeli kọlù, lẹhin igbati nwọn ti Egipti jade wá:


Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ani dé òke Sioni (ti iṣe Hermoni,)


Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i.


Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.


Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa.


Pẹlu rẹ̀ awọn ọmọ Reubeni ati awọn ọmọ Gadi ti gbà ilẹ-iní wọn, ti Mose fi fun wọn ni ìha keji Jordani ni ìha ìla õrùn, bi Mose iranṣẹ OLUWA ti fi fun wọn;


Njẹ nisisiyi OLUWA Ọlọrun nyin ti fi isimi fun awọn arakunrin nyin, gẹgẹ bi o ti sọ fun wọn: njẹ nisisiyi ẹ pada, ki ẹ si lọ sinu agọ́ nyin, ati si ilẹ-iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA ti fun nyin ni ìha keji Jordani.


Nigbana ni o rìn lãrin aginjù o si yi ilẹ Edomu, ati ilẹ Moabu ká, o si yọ ni ìha ìla-õrùn ilẹ Moabu, nwọn si dó si ìha keji Arnoni, ṣugbọn nwọn kò wá sinu àla Moabu, nitoripe Arnoni ni àla Moabu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan