Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:8 - Bibeli Mimọ

8 OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

8 OLUWA fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́, àwọn ọmọ ogun Israẹli sì bẹ̀rẹ̀ sí pa wọ́n. Wọ́n lé wọn títí dé Sidoni ati Misirefoti Maimu, ati apá ìlà oòrùn títí dé àfonífojì Misipa, wọ́n pa wọ́n títí tí kò fi ku ẹyọ ẹnìkan.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

8 Olúwa sì fi wọ́n lé Israẹli lọ́wọ́. Wọ́n ṣẹ́gun wọn, wọ́n sì lépa wọn ní gbogbo ọ̀nà títí dé Sidoni ńlá, sí Misrefoti-Maimu, àti sí Àfonífojì Mispa ní ìlà-oòrùn, títí tí kò fi ku ẹnìkankan sílẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:8
13 Iomraidhean Croise  

Kenaani si bí Sidoni akọbi rẹ̀, ati Heti,


Sebuloni ni yio ma gbé ebute okun: on ni yio si ma wà fun ebute ọkọ̀; ipinlẹ rẹ̀ yio si dé Sidoni.


Nwọn si wá si Gileadi, ati si ilẹ Tatimhodṣi; nwọn si wá si Dan-jaani ati yikakiri si Sidoni,


Ki oju ki o tì ọ, Iwọ Sidoni: nitori okun ti sọ̀rọ, ani agbara okun, wipe, Emi kò rọbi, bẹ̃ni emi kò bi ọmọ, bẹ̃li emi kò tọ́ ọdọmọkunrin dàgba, bẹ̃ni emi kò tọ́ wundia dàgba.


Ati Hamati pẹlu yio ṣe ãla rẹ̀: Tire ati Sidoni bi o tilẹ ṣe ọlọgbọ́n gidigidi.


Nigbati OLUWA Ọlọrun rẹ ba fi wọn lé ọ lọwọ, iwọ o si kọlù wọn; ki o si run wọn patapata; iwọ kò gbọdọ bá wọn dá majẹmu, bẹ̃ni iwọ kò gbọdọ ṣãnu fun wọn:


Iwọ o si mọ̀ li oni pe, OLUWA Ọlọrun rẹ on ni ngòke ṣaju rẹ lọ bi iná ajonirun; yio pa wọn run, on o si rẹ̀ wọn silẹ niwaju rẹ: iwọ o si lé wọn jade, iwọ o si pa wọn run kánkán, bi OLUWA ti wi fun ọ.


O si ṣe, nigbati Joṣua ati awọn ọmọ Israeli pa wọn ni ipakupa tán, titi a fi run wọn, ti awọn ti o kù ninu wọn wọ̀ inu ilu olodi lọ,


Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa.


Bẹ̃ni Joṣua, ati gbogbo awọn ọmọ-ogun pẹlu rẹ̀, yọ si wọn lojijì ni ibi omi Meromu, nwọn si kọlù wọn.


Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ.


Ati Ebroni, ati Rehobu, ati Hammoni, ati Kana, ani titi dé Sidoni nla;


OLUWA si fun wọn ni isimi yiká kiri, gẹgẹ bi gbogbo eyiti o bura fun awọn baba wọn: kò si sí ọkunrin kan ninu gbogbo awọn ọtá wọn ti o duro niwaju wọn; OLUWA fi gbogbo awọn ọtá wọn lé wọn lọwọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan