Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:4 - Bibeli Mimọ

4 Nwọn si jade, awọn ati gbogbo ogun wọn pẹlu wọn, ọ̀pọlọpọ enia, bi yanrin ti mbẹ li eti okun fun ọ̀pọ, ati ẹṣin ati kẹkẹ́ pipọ̀pipọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 Gbogbo wọn jáde pẹlu gbogbo ọmọ ogun wọn, wọ́n pọ̀ yanturu bí eṣú. Wọ́n dàbí iyanrìn etí òkun. Ẹṣin ati kẹ̀kẹ́ ogun wọn kò lóǹkà.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 Wọ́n sì jáde pẹ̀lú gbogbo ogun wọn àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ẹṣin àti kẹ̀kẹ́ ogun ńlá, wọ́n sì pọ̀, gẹ́gẹ́ bí iyanrìn etí Òkun

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:4
8 Iomraidhean Croise  

Pe ni bibukún emi o bukún fun ọ, ati ni bíbisi emi o mu irú-ọmọ rẹ bísi i bi irawọ oju-ọrun, ati bi iyanrin eti okun; irú-ọmọ rẹ ni yio si ni ẹnubode awọn ọta wọn;


Iwọ si wipe, Nitõtọ emi o ṣe ọ ni rere, emi o si ṣe irú-ọmọ rẹ bi iyanrin okun, ti a kò le kà fun ọ̀pọlọpọ.


Nitorina emi damọ̀ran pe, Ki gbogbo Israeli wọjọ pọ̀ sọ̀dọ rẹ, lati Dani titi dé Beerṣeba, gẹgẹ bi yanrin ti o wà leti okun fun ọ̀pọlọpọ; ati pe, ki iwọ tikararẹ ki o lọ si ogun na.


Juda ati Israeli pọ̀ gẹgẹ bi iyanrin ti mbẹ li eti okun ni ọ̀pọlọpọ, nwọn njẹ, nwọn si nmu, nwọn si nṣe ariya.


Nwọn wolẹ, nwọn si ṣubu: ṣugbọn awa dide awa si duro ṣinṣin.


Gbogbo awọn ọba wọnyi si pejọ pọ̀, nwọn wá nwọn si dó ṣọkan ni ibi omi Meromu, lati fi ijà fun Israeli.


Awọn Midiani ati awọn Amaleki, ati gbogbo awọn ọmọ ìha ìla-õrùn tò lọ titi li afonifoji gẹgẹ bi eṣú li ọ̀pọlọpọ; ibakasiẹ wọn kò si ní iye, bi iyanrin ti mbẹ leti okun li ọ̀pọlọpọ.


Awọn Filistini kó ara wọn jọ lati ba Israeli jà, ẹgbã-mẹ̃dogun kẹkẹ, ẹgbãta ọkunrin ẹlẹṣin, enia si pọ̀ bi yanrin leti okun; nwọn si goke, nwọn do ni Mikmaṣi ni iha ila õrun Bet-Afeni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan