Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:3 - Bibeli Mimọ

3 Ati si awọn ara Kenaani ni ìha ìla-õrùn ati ni ìha ìwọ-õrùn, ati awọn Amori, ati si awọn Hitti, ati si awọn Perissi, ati si awọn Jebusi lori òke, ati si awọn Hifi nisalẹ Hermoni ni ilẹ Mispa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Ó ranṣẹ sí àwọn ará Kenaani ní ìhà ìlà oòrùn, ati ti ìwọ̀ oòrùn, ati àwọn ará Amori, ati àwọn ará Hiti, ati àwọn ará Perisi, ati àwọn ará Jebusi ní àwọn agbègbè olókè, ati àwọn ará Hifi tí wọ́n wà ní abẹ́ òkè Herimoni ní ilẹ̀ Misipa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 sí àwọn ará Kenaani ní ìlà-oòrùn àti ìwọ̀-oòrùn; sí àwọn Amori, Hiti, Peresi àti Jebusi ní orí òkè; àti sí àwọn Hifi ní ìsàlẹ̀ Hermoni ní agbègbè Mispa.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:3
30 Iomraidhean Croise  

Ati Mispa; nitori ti o wipe, Ki OLUWA ki o ma ṣọ́ temi tirẹ nigbati a o yà kuro lọdọ ara wa.


Nigbati angeli na si nawọ́ rẹ̀ si Jerusalemu lati pa a run, Oluwa si kãnu nitori ibi na, o si sọ fun angeli ti npa awọn enia na run pe, O to: da ọwọ́ rẹ duro wayi. Angeli Oluwa na si wà nibi ipaka Arauna ara Jebusi.


Nwọn si wá si ilu olodi Tire, ati si gbogbo ilu awọn Hifi, ati ti awọn ara Kenaani: nwọn si jade lọ siha gusu ti Juda, ani si Beerṣeba.


Nigbana ni Asa ọba kede ká gbogbo Juda, kò da ẹnikan si: nwọn si kó okuta Rama kuro, ati igi rẹ̀, ti Baaṣa fi kọle: Asa ọba si fi wọn kọ́ Geba ti Benjamini, ati Mispa.


Gbogbo enia ti o kù ninu awọn ara Amori, ara Hitti, Perisi, Hifi ati Jebusi, ti kì iṣe ti inu awọn ọmọ Israeli.


Bi ìri Hermoni ti o ṣàn sori òke Sioni: nitori nibẹ ni Oluwa gbe paṣẹ ibukún, ani ìye lailai.


Ariwa ati gusù iwọ li o ti da wọn: Taboru ati Hermoni yio ma yọ̀ li orukọ rẹ.


Ki a lọ kuro ni Lebanoni, iyawo mi, ki a lọ kuro ni Lebanoni: wò lati ori òke Amana, lati ori òke Ṣeniri ati Hermoni, lati ibi ihò kiniun, lati òke awọn ẹkùn.


Bi o ṣe ti emi, wò o, emi o ma gbe Mispa, lati sìn awọn ara Kaldea, ti yio tọ wa wá; ṣugbọn ẹnyin ẹ kó ọti-waini jọ, ati eso-igi, ati ororo, ki ẹ si fi sinu ohun-elo nyin, ki ẹ si gbe inu ilu nyin ti ẹnyin ti gbà.


Jeremiah si lọ sọdọ Gedaliah, ọmọ Ahikamu, ni Mispa; o si mba a gbe lãrin awọn enia, ti o kù ni ilẹ na.


Bẹ̃ni gbogbo awọn enia, ti Iṣmaeli ti kó lọ ni igbekun lati Mispa, yi oju wọn, nwọn si yipada, nwọn si lọ sọdọ Johanani, ọmọ Karea.


Pẹlupẹlu Iṣmaeli pa gbogbo awọn ara Juda ti o wà pẹlu rẹ̀, ani pẹlu Gedaliah, ni Mispa, ati awọn ara Kaldea, ti a ri nibẹ, awọn ologun.


Awọn ara Amaleki si ngbé ilẹ ìha gusù: ati awọn Hitti, ati awọn Jebusi, ati awọn Amori, ngbé ori-òke: awọn ara Kenaani si ngbé ẹba okun, ati ni àgbegbe Jordani.


Lati Aroeri lọ, ti mbẹ leti afonifoji Arnoni, ani dé òke Sioni (ti iṣe Hermoni,)


NIGBATI OLUWA Ọlọrun rẹ ba mú ọ dé ilẹ na nibiti iwọ gbé nlọ lati gbà a, ti o ba lé orilẹ-ède pupọ̀ kuro niwaju rẹ, awọn Hitti, ati awọn Girgaṣi, ati awọn Amori, ati awọn ara Kenaani, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi, orilẹ-ède meje, ti o pọ̀ ti o si lagbara jù ọ lọ;


Lati òke Halaki lọ, ti o lọ soke Seiri, ani dé Baali-gadi ni afonifoji Lebanoni nisalẹ òke Hermoni: ati gbogbo awọn ọba wọn li o kó, o si kọlù wọn, o si pa wọn.


OLUWA si fi wọn lé Israeli lọwọ, nwọn si kọlù wọn, nwọn si lé wọn titi dé Sidoni nla ati titi dé Misrefoti-maimu, ati dé afonifoji Mispa ni ìha ìla-õrùn; nwọn si pa wọn tobẹ̃ ti kò kù ẹnikan silẹ fun wọn.


Ati Gileadi, ati àgbegbe awọn Geṣuri ati awọn Maakati, ati gbogbo òke Hermoni, ati gbogbo Baṣani dé Saleka;


Ati ilẹ awọn Gebali, ati gbogbo Lebanoni ni ìha ìla-õrùn, lati Baali-gadi nisalẹ òke Hermoni titi o fi dé atiwọ̀ Hamati:


Ati Dilani, ati Mispe, ati Jokteeli;


Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.


Ati Mispe, ati Kefira, ati Mosa;


Joṣua si wipe, Nipa eyi li ẹnyin o mọ̀ pe Ọlọrun alãye mbẹ lãrin nyin, ati pe dajudaju on o lé awọn ara Kenaani, ati awọn Hitti, ati awọn Hifi, ati awọn Perissi, ati awọn Girgaṣi ati awọn Amori, ati awọn Jebusi, kuro niwaju nyin.


NIGBANA ni gbogbo awọn ọmọ Israeli jade lọ, ijọ awọn enia si wọjọ pọ̀ bi ọkunrin kan, lati Dani lọ titi o fi dé Beeri-ṣeba, pẹlu ilẹ Gileadi, si ọdọ OLUWA ni Mispa.


Awọn ọmọ Israeli si wipe, Tali o wà ninu gbogbo awọn ẹ̀ya Israeli ti kò bá ijọ gòke tọ̀ OLUWA wá? Nitoripe nwọn ti bura nla niti ẹniti kò ba tọ̀ OLUWA wá ni Mispe, wipe, Pipa li a o pa a.


Nwọn si wipe, Ewo ni ninu awọn ẹ̀ya Israeli ti kò tọ̀ OLUWA wá ni Mispe? Si kiyesi i, kò sí ẹnikan ni ibudó ti o ti Jabeṣi-gileadi wá si ijọ.


Awọn ijoye Filistini marun, ati gbogbo awọn Kenaani, ati awọn ara Sidoni, ati awọn Hifi ti ngbé òke Lebanoni, lati òke Baali-hermoni lọ dé atiwọ̀ Hamati.


Awọn ọmọ Israeli si joko lãrin awọn ara Kenaani; ati awọn Hitti, ati awọn Amori, ati awọn Perissi, ati awọn Hifi, ati awọn Jebusi:


Samueli si pe gbogbo enia jọ siwaju Oluwa ni Mispe.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan