Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:2 - Bibeli Mimọ

2 Ati si awọn ọba ti mbẹ ni ìha ariwa, lori òke, ati ti pẹtẹlẹ̀ ni ìha gusù ti Kinnerotu, ati ni ilẹ titẹju, ati ni ilẹ òke Doru ni ìha ìwọ-õrùn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 ati sí àwọn ọba tí wọ́n wà ní àwọn ìlú olókè ti apá ìhà àríwá, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Araba ní ìhà gúsù Kineroti, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní ẹsẹ̀ òkè, ati sí àwọn tí wọ́n wà ní Nafoti-dori ní apá ìwọ̀ oòrùn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 àti sí àwọn ọba ìhà àríwá tí wọ́n wà ní orí òkè ní aginjù, gúúsù ti Kinnereti, ní ẹsẹ̀ òkè ìwọ̀-oòrùn àti ní Nafoti Dori ní ìwọ̀-oòrùn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:2
14 Iomraidhean Croise  

Bẹ̃ni Benhadadi fi eti si ti Asa ọba, o si rán awọn alagbara olori-ogun ti o ni, si ilu Israeli wọnnì, o si kọlu Ijoni, ati Dani ati Abel-bet-maaka, ati gbogbo Kenneroti pẹlu gbogbo ilẹ Naftali.


Ọmọ Abinadabu, ni gbogbo agbègbe Dori: ti o ni Tafati, ọmọbinrin Solomoni, li aya.


Ki opinlẹ na ki o si ti Ṣefamu sọkalẹ lọ si Ribla, ni ìha ìla-õrùn Aini; ki opinlẹ na ki o si sọkalẹ lọ, ki o si dé ìha okun Kinnereti ni ìha ìla-õrùn.


Ni ijọ wọnyi ni Maria si dide, o lọ kánkan si ilẹ-òke, si ilu kan ni Juda;


O si ṣe, nigbati ijọ enia ṣù mọ́ ọ lati gbọ́ ọ̀rọ Ọlọrun, ti o si duro leti adagun Genesareti,


Bẹ̃ni Joṣua kọlù gbogbo ilẹ, ilẹ òke, ati ti Gusù, ati ti pẹtẹlẹ̀, ati ti ẹsẹ̀-òke, ati awọn ọba wọn gbogbo; kò kù ẹnikan silẹ: ṣugbọn o pa ohun gbogbo ti nmí run patapata, gẹgẹ bi OLUWA, Ọlọrun Israeli, ti pa a laṣẹ.


Awọn ọkunrin Gibeoni si ranṣẹ si Joṣua ni ibudó ni Gilgali, wipe, Má ṣe fà ọwọ́ rẹ sẹhin kuro lọdọ awọn iranṣẹ rẹ; gòke tọ̀ wa wá kánkán, ki o si gbà wa, ki o si ràn wa lọwọ: nitoriti gbogbo awọn ọba Amori ti ngbé ori òke kójọ pọ̀ si wa.


Bẹ̃ni Joṣua gbà gbogbo ilẹ na, ilẹ òke, ati gbogbo ilẹ Gusù, ati gbogbo ilẹ Goṣeni, ati ilẹ titẹju, ati pẹtẹlẹ̀, ati ilẹ òke Israeli, ati ilẹ titẹju rẹ̀;


Li akokò na ni Joṣua wá, ti o si ke awọn ọmọ Anaki kuro ni ilẹ òke, kuro ni Hebroni, kuro ni Debiri, kuro ni Anabu, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Juda, ati kuro ni gbogbo ilẹ òke Israeli: Joṣua run wọn patapata pẹlu ilu wọn.


Ọba Doru, li òke Doru, ọkan; ọba awọn orilẹ-ède Gilgali, ọkan;


Ati ni pẹtẹlẹ̀ lọ dé okun Kinnerotu ni ìha ìla-õrùn, ati titi dé okun pẹtẹlẹ̀, ani Okun Iyọ̀ ni ìha ìla-õrun, li ọ̀na Beti-jeṣimotu; ati lati gusù lọ nisalẹ ẹsẹ̀-òke Pisga:


Ati ni afonifoji, Beti-haramu, ati Beti-nimra, ati Sukkotu, ati Safoni, iyokù ilẹ-ọba Sihoni ọba Heṣboni, Jordani ati àgbegbe rẹ̀, titi dé ìha opín okun Kinnereti ni ìha keji Jordani ni ìha ìla-õrùn.


Manasse si ní ni Issakari ati ni Aṣeri, Beti-ṣeani ati awọn ilu rẹ̀, ati Ibleamu ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Dori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Enidori ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Taanaki ati awọn ilu rẹ̀, ati awọn ara Megiddo ati awọn ilu rẹ̀, ani òke mẹta na.


Manasse kò si lé awọn ara Beti-seani ati ilu rẹ̀ wọnni jade, tabi awọn ara Taanaki ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Dori ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Ibleamu ati ilu rẹ̀ wọnni, tabi awọn ara Megiddo ati ilu rẹ̀ wọnni: ṣugbọn awọn ara Kenaani ngbé ilẹ na.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan