Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 11:1 - Bibeli Mimọ

1 O si ṣe, nigbati Jabini ọba Hasoru gbọ́ nkan wọnyi, o ranṣẹ si Jobabu ọba Madoni, ati si ọba Ṣimroni, ati si ọba Akṣafu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí Jabini ọba Hasori, gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀, ó ranṣẹ sí Jobabu, ọba Madoni, ati sí ọba Ṣimironi, ati sí ọba Akiṣafu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Nígbà tí Jabini ọba Hasori gbọ́ nǹkan wọ̀nyí, ó ránṣẹ́ sí Jobabu ọba Madoni, sí ọba Ṣimroni àti Akṣafu,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 11:1
19 Iomraidhean Croise  

Nigbati awọn ara Siria si ri pe nwọn di bibì ṣubu niwaju Israeli, nwọn si ko ara wọn jọ.


Ọmọ Abinadabu, ni gbogbo agbègbe Dori: ti o ni Tafati, ọmọbinrin Solomoni, li aya.


Idi awọn asìnru ti Solomoni kojọ ni eyi; lati kọ́ ile Oluwa, ati ile on tikararẹ̀, ati Millo, ati odi Jerusalemu, ati Hasori ati Megiddo, ati Geseri.


Li ọjọ Peka ọba Israeli ni Tiglat-pileseri ọba Assiria de, o si kó Ijoni, ati Abel-betmaaka, ati Janoa, ati Kedeṣi, ati Hasori, ati Gileadi, ati Galili, gbogbo ilẹ Naftali, o si kó wọn ni igbèkun lọ si Assiria.


Oluwa, ọwọ́ rẹ gbe soke, nwọn kì yio ri, ṣugbọn nwọn o ri, oju o si tì wọn nitori ilara wọn si awọn enia; nitõtọ, iná awọn ọta rẹ yio jẹ wọn run.


Nigbati iwọ ba nlà omi kọja, emi o pẹlu rẹ; ati lãrin odò, nwọn ki yio bò ọ mọlẹ: nigbati iwọ ba nrìn ninu iná, ki yio jo ọ, bẹ̃ni ọwọ́-iná ki yio ràn ọ.


Joṣua si pada, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀, si ibudó ni Gilgali.


Joṣua si pada li akokò na, o si kó Hasoru, o si fi idà pa ọba rẹ̀: nitori li atijọ́ rí Hasoru li olori gbogbo ilẹ-ọba wọnni.


Ọba Madoni, ọkan; ọba Hasoru, ọkan;


Ọba Ṣimroni-meroni, ọkan; ọba Akṣafu, ọkan;


Ati Adama, ati Rama, ati Hasoru;


Nwọn si kó ara wọn jọ, lati fi ìmọ kan bá Joṣua ati Israeli jà.


Ṣugbọn Sisera ti fi ẹsẹ̀ rẹ̀ sálọ si agọ́ Jaeli aya Heberi ọmọ Keni: nitoriti alafia wà lãrin Jabini ọba Hasori ati ile Heberi ọmọ Keni.


OLUWA si tà wọn si ọwọ́ Jabini ọba Kenaani, ẹniti o jọba ni Hasori; olori ogun ẹniti iṣe Sisera, ẹniti ngbé Haroṣeti ti awọn orilẹ-ède.


Awọn ọba wá nwọn jà; nigbana li awọn ọba Kenaani jà ni Taanaki leti odò Megiddo: nwọn kò si gbà ère owo.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan