Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:4 - Bibeli Mimọ

4 Ẹ gòke tọ̀ mi wá, ki ẹ si ràn mi lọwọ, ki awa ki o le kọlù Gibeoni: nitoriti o bá Joṣua ati awọn ọmọ Israeli ṣọrẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

4 “Ẹ wá ràn mí lọ́wọ́. Ẹ jẹ́ kí á kọlu Gibeoni, nítorí pé ó ti bá Joṣua ati àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

4 “Ẹ gòkè wá, kí ẹ sì ràn mi lọ́wọ́ láti kọlu Gibeoni, nítorí tí ó ti wà ní ìrẹ́pọ̀ pẹ̀lú Joṣua àti àwọn ará Israẹli.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:4
15 Iomraidhean Croise  

Nigbana ni Jesu wi fun awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ pe, Bi ẹnikan ba nfẹ lati tọ̀ mi lẹhin, ki o sẹ ara rẹ̀, ki o si gbé agbelebu rẹ̀, ki o si mã tọ̀ mi lẹhin.


Ibaṣepe ẹnyin iṣe ti aiye, aiye iba fẹ awọn tirẹ̀; ṣugbọn nitoriti ẹnyin kì iṣe ti aiye, ṣugbọn emi ti yàn nyin kuro ninu aiye, nitori eyi li aiye ṣe korira nyin.


Nwọn nkigbe wipe, Ẹnyin enia Israeli, ẹ gbà wa: Eyi li ọkunrin na, ti nkọ́ gbogbo enia nibigbogbo lòdi si awọn enia, ati si ofin, ati si ibi yi: ati pẹlu o si mu awọn ara Hellene wá si tẹmpili, o si ti ba ibi mimọ́ yi jẹ.


Nitõtọ, gbogbo awọn ti o fẹ mã gbé igbé ìwa-bi-Ọlọrun ninu Kristi Jesu, yio farada inunibini.


Ẹnyin panṣaga ọkunrin, ati panṣaga obinrin, ẹ kò mọ̀ pe ìbarẹ́ aiye ìṣọtá Ọlọrun ni? nitorina ẹnikẹni ti o ba fẹ lati jẹ́ ọrẹ aiye di ọtá Ọlọrun.


O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn;


Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u.


Joṣua si bá wọn ṣọrẹ, o si bá wọn dá majẹmu lati da wọn si: awọn olori ijọ enia fi OLUWA Ọlọrun Israeli bura fun wọn.


Eyi ti o yà wọn lẹnu pe ẹnyin kò ba wọn súré sinu iru aṣejù iwa wọbia wọn, ti nwọn sì nsọrọ nyin ni buburu,


Nitori ẹmi èṣu ni wọn, ti nṣe iṣẹ-iyanu, awọn ti njade lọ sọdọ awọn ọba gbogbo ilẹ aiye, lati gbá wọn jọ si ogun ọjọ nla Ọlọrun Olodumare.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan