Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:3 - Bibeli Mimọ

3 Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Nítorí náà, Adonisedeki ọba Jerusalẹmu ranṣẹ sí Hohamu ọba Heburoni, Piramu ọba Jarimutu, Jafia ọba Lakiṣi ati Debiri ọba Egiloni, pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Nítorí náà Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu bẹ Hohamu ọba Hebroni, Piramu ọba Jarmatu, Jafia ọba Lakiṣi àti Debiri ọba Egloni. Wí pe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:3
19 Iomraidhean Croise  

Sara si kú ni Kirjat-arba; eyi na ni Hebroni ni ilẹ Kenaani: Abrahamu si wá lati ṣọ̀fọ Sara ati lati sọkun rẹ̀.


O si wi fun u pe, Mo bẹ̀ ọ, lọ wò alafia awọn arakunrin rẹ, ati alafia awọn agbo-ẹran; ki o si mú ihin pada fun mi wá. Bẹ̃li o si rán a lati afonifoji Hebroni lọ, on si dé Ṣekemu.


Gbogbo ọjọ ti Dafidi fi jọba ni Hebroni lori ile Juda jẹ ọdun meje pẹlu oṣù mẹfa.


Hesekiah ọba Juda si ranṣẹ si ọba Assiria ni Lakiṣi, wipe, Mo ti ṣẹ̀; padà lẹhin mi: eyiti iwọ ba bù fun mi li emi o rù. Ọba Assiria si bù ọ̃dunrun talenti fadakà, ati ọgbọ̀n talenti wura fun Hesekiah ọba Juda.


Ọba Assiria si rán Tartani, ati Rabsarisi, ati Rabṣake, lati Lakiṣi lọ si ọdọ Hesekiah ọba pẹlu ogun nla si Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn si de Jerusalemu. Nwọn si gòke wá, nwọn de, nwọn si duro leti idari omi abàta òke, ti mbẹ li eti òpopo pápa afọṣọ.


Ati Adoraimu, ati Lakiṣi, ati Aseki,


Ni wakati na ogun ọba Babeli mba Jerusalemu jà, ati gbogbo ilu Juda ti o kù, Lakiṣi, ati Aseka: wọnyi li o kù ninu ilu Juda, nitori nwọn jẹ ilu olodi.


Iwọ ara Lakiṣi, di kẹkẹ mọ ẹranko ti o yara: on ni ibẹrẹ ẹ̀ṣẹ si ọmọbinrin Sioni: nitori a ri irekọja Israeli ninu rẹ.


Nwọn si ti ìha gusù gòke lọ, nwọn si dé Hebroni; nibiti Ahimani, Ṣeṣai, ati Talmai, awọn ọmọ Anaki gbé wà. (A ti tẹ̀ Hebroni dò li ọdún meje ṣaju Soani ni Egipti.)


O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn;


Nwọn si ṣe bẹ̃, nwọn si mú awọn ọba mararun nì jade lati inu ihò na tọ̀ ọ wá, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni.


Lati Lakiṣi Joṣua kọja lọ si Egloni, ati gbogbo Israeli pẹlu rẹ̀; nwọn si dótì i, nwọn si fi ijà fun u;


Awọn ọba Amori mararun, ọba Jerusalemu, ọba Hebroni, ọba Jarmutu, ọba Lakiṣi, ati ọba Egloni, kó ara wọn jọ, nwọn si gòke, awọn ati gbogbo ogun wọn, nwọn si dótì Gibeoni, nwọn si fi ìja fun u.


Orukọ Hebroni lailai rí a ma jẹ́ Kiriati-arba; Arba jẹ́ enia nla kan ninu awọn ọmọ Anaki. Ilẹ na si simi lọwọ ogun.


Ati Humta, ati Kiriati-arba (ti iṣe Hebroni), ati Siori; ilu meṣan pẹlu ileto wọn.


Bi o si ṣe ti awọn Jebusi nì, awọn ara Jerusalemu, awọn ọmọ Juda kò le lé wọn jade: ṣugbọn awọn Jebusi mbá awọn ọmọ Juda gbé ni Jerusalemu, titi di oni-oloni.


Ati Sela, Elefu, ati Jebusi (ti iṣe Jerusalemu), Gibeati, ati Kitiria; ilu mẹrinla pẹlu ileto wọn. Eyi ni ilẹ-iní awọn ọmọ Benjamini gẹgẹ bi idile wọn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan