Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:2 - Bibeli Mimọ

2 Nwọn bẹ̀ru pipọ̀, nitoriti Gibeoni ṣe ilu nla, bi ọkan ninu awọn ilu ọba, ati nitoriti o tobi jù Ai lọ, ati gbogbo ọkunrin inu rẹ̀ jẹ́ alagbara.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

2 ẹ̀rù bà á gidigidi, nítorí pé ìlú ńlá ni ìlú Gibeoni bí ọ̀kan ninu àwọn ìlú ọba aládé. Gibeoni tóbi ju ìlú Ai lọ, akọni sì ni gbogbo àwọn ọkunrin ibẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

2 Ìbẹ̀rù sì mú òun àti àwọn ènìyàn rẹ̀ torí pé Gibeoni jẹ́ ìlú tí ó ṣe pàtàkì, bí ọ̀kan nínú àwọn ìlú ọba; ó tóbi ju Ai lọ, gbogbo ọkùnrin rẹ̀ ní ó jẹ́ jagunjagun.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:2
16 Iomraidhean Croise  

Joabu si ba Rabba ti awọn ọmọ Ammoni jagun, o si gbà ilu ọba wọn.


Ibẹ̀ru enia buburu mbọwá ba a: ṣugbọn ifẹ olododo li a o fi fun u.


Kò sí ọkunrin kan ti yio le duro niwaju nyin: OLUWA Ọlọrun nyin, yio fi ìbẹru nyin ati ìfoiya nyin sara gbogbo ilẹ ti ẹnyin o tẹ̀, bi on ti wi fun nyin.


Li oni yi li emi o bẹ̀rẹsi fi ìfoya rẹ, ati ẹ̀ru rẹ sara awọn orilẹ-ède ti mbẹ ni gbogbo abẹ ọrun, ti yio gburó rẹ, ti yio si warìri, ti yio si ṣe ipàiya nitori rẹ.


Gbogbo enia aiye yio si ri pe orukọ OLUWA li a fi npè ọ; nwọn o si ma bẹ̀ru rẹ.


Bikoṣe ireti idajọ ti o ba ni lẹrù, ati ti ibinu ti o muná, ti yio pa awọn ọtá run.


Ohun ẹ̀ru ni lati ṣubu si ọwọ́ Ọlọrun alãye.


Nwọn si wi fun Joṣua pe, Nitõtọ li OLUWA ti fi gbogbo ilẹ na lé wa lọwọ; nitoripe ọkàn gbogbo awọn ara ilẹ yi di omi nitori wa.


Nwọn si da Joṣua lohùn wipe, Nitoriti a sọ fun awọn iranṣẹ rẹ dajudaju, bi OLUWA Ọlọrun rẹ ti paṣẹ fun Mose iranṣẹ rẹ̀, lati fun nyin ni gbogbo ilẹ na, ati lati pa gbogbo awọn ara ilẹ na run kuro niwaju nyin; nitorina awa bẹ̀ru nyin gidigidi nitori ẹmi wa, a si ṣe nkan yi.


Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai,


Dafidi si wi fun Akiṣi pe, Bi o ba jẹ pe emi ri ore ọfẹ loju rẹ, jẹ ki wọn ki o fun mi ni ibi kan ninu awọn ileto wọnni; emi o ma gbe ibẹ: ẽṣe ti iranṣẹ rẹ yio si ma ba ọ gbe ni ilu ọba?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan