Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 10:1 - Bibeli Mimọ

1 O SI ṣe, nigbati Adoni-sedeki ọba Jerusalemu gbọ́ pe Joṣua ti kó Ai, ti o si pa a run patapata; bi o ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀, bẹ̃li o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀; ati bi awọn ara Gibeoni ti bá Israeli ṣọrẹ, ti nwọn si ngbé ãrin wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Nígbà tí Adonisedeki, ọba Jerusalẹmu, gbọ́ bí Joṣua ṣe gba ìlú Ai, ati pé ó pa ìlú Ai ati ọba rẹ̀ run, bí ó ti ṣe sí ìlú Jẹriko ati ọba rẹ̀; ati pé àwọn ará Gibeoni ti bá àwọn ọmọ Israẹli dá majẹmu alaafia, wọ́n sì ń gbé ààrin wọn,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Ní báyìí tí Adoni-Sedeki ọba Jerusalẹmu gbọ́ pé Joṣua ti gba Ai, tí ó sì ti pa wọ́n pátápátá; tí ó sì ṣe sí Ai àti ọba rẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe sí Jeriko àti ọba rẹ̀, àti bí àwọn ènìyàn Gibeoni ti ṣe àdéhùn àlàáfíà pẹ̀lú Israẹli, tí wọ́n sì ń gbé nítòsí wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 10:1
10 Iomraidhean Croise  

Melkisedeki ọba Salemu si mu onjẹ ati ọti waini jade wá: on a si ma ṣe alufa Ọlọrun Ọga-ogo.


NITORI Melkisedeki yi, ọba Salemu, alufa Ọlọrun Ọgá-ogo, ẹniti o pade Abrahamu bi o ti npada lati ibi pipa awọn ọba bọ̀, ti o si sure fun u;


Nitorina Adoni-sedeki ọba Jerusalemu ranṣẹ si Hohamu ọba Hebroni, ati si Piramu ọba Jarmutu, ati si Jafia ọba Lakiṣi, ati si Debiri ọba Egloni, wipe,


Nwọn si fi oju idà pa gbogbo ohun ti o wà ni ilu na run, ati ọkunrin ati obinrin, ati ewe ati àgba, ati akọ-mãlu, ati agutan, ati kẹtẹkẹtẹ.


Iwọ o si ṣe si Ai ati si ọba rẹ̀ gẹgẹ bi iwọ ti ṣe si Jeriko ati si ọba rẹ̀: kìki ikogun rẹ̀, ati ohun-ọ̀sin rẹ̀, li ẹnyin o mú ni ikogun fun ara nyin: rán enia lọ iba lẹhin ilu na.


Nigbati Joṣua ati gbogbo Israeli ri bi awọn ti o ba ti gbà ilu, ti ẹ̃fi ilu na si gòke, nwọn si yipada, nwọn si pa awọn ọkunrin Ai.


Ṣugbọn nigbati awọn ara Gibeoni gbọ́ ohun ti Joṣua ṣe si Jeriko ati si Ai,


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan