Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:6 - Bibeli Mimọ

6 Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitori iwọ ni yio pín ilẹ na fun awọn enia yi, ilẹ ti mo ti bura fun awọn baba wọn lati fi fun wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

6 Múra, kí o sì ṣe ọkàn gírí, nítorí ìwọ ni o óo jẹ́ kí àwọn eniyan wọnyi gba ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba wọn, pé n óo fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

6 “Jẹ́ alágbára kí o sì mú àyà le, nítorí ìwọ ni yóò ṣe amọ̀nà àwọn ènìyàn wọ̀nyí, láti lè jogún ilẹ̀ tí mo ti búra fún àwọn baba ńlá a wọn láti fi fún wọn.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:6
36 Iomraidhean Croise  

OLUWA si fi ara hàn fun Abramu, o si wipe, Irú-ọmọ rẹ li emi o fi ilẹ yi fun: nibẹ̀ li o si tẹ́ pẹpẹ fun OLUWA ti o fi ara hàn a.


Mã ṣe atipo ni ilẹ yi, emi o si pẹlu rẹ, emi o si bukún u fun ọ; nitori iwọ ati irú-ọmọ rẹ, li emi o fi gbogbo ilẹ wọnyi fun, emi o si mu ara ti mo bú fun Abrahamu, baba rẹ, ṣẹ.


Mu ọkàn le, jẹ ki a ṣe onigboya nitori awọn enia wa, ati nitori awọn ilu Ọlọrun wa; Oluwa o si ṣe eyi ti o dara li oju rẹ̀.


Emi nlọ si ọ̀na gbogbo aiye: nitorina mu ara rẹ le, ki o si fi ara rẹ̀ hàn bi ọkunrin.


Nigbana ni iwọ o ma pọ̀ si i, bi iwọ ba ṣe akiyesi lati mu aṣẹ ati idajọ ti Oluwa pa fun Mose ṣẹ niti Israeli: mura giri ki o si ṣe onigboya, má bẹ̀ru bẹ̃ni ki aiya ki o máṣe fò ọ.


Wò o nisisiyi: nitori Oluwa ti yàn ọ lati kọ́ ile kan fun ibi mimọ́, mura le, ki iwọ si ṣe e.


Dafidi si sọ fun Solomoni ọmọ rẹ̀ pe, murale ki o si gboyà, ki o si ṣiṣẹ: má bẹ̀ru, bẹ̃ni ki o máṣe dãmu: nitori Oluwa Ọlọrun, ani Ọlọrun mi wà pẹlu rẹ; on kì yio yẹ̀ ọ, bẹ̃ni kì yio kọ̀ ọ silẹ titi iwọ o fi pari gbogbo iṣẹ fun ìsin ile Oluwa.


Ṣugbọn ẹnyin mu ara le, ki ẹ má si dẹ ọwọ nyin: nitori iṣẹ nyin yio ni ère.


Si kiyesi i, bi nwọn ti san a pada fun wa; lati wá le wa jade kuro ninu ini rẹ, ti iwọ ti fi fun wa lati ni.


Iwọ ha kọ́ Ọlọrun wa, ti o ti le awọn ara ilẹ yi jade niwaju Israeli enia rẹ, ti o si fi fun iru-ọmọ Abrahamu, ọrẹ rẹ lailai?


Duro de Oluwa; ki o si tújuka, yio si mu ọ li aiya le: mo ni, duro de Oluwa.


O si wipe, iwọ ọkunrin olufẹ gidigidi, má bẹ̀ru: alafia ni fun ọ, mu ara le. Ani mu ara le, Nigbati on ba mi sọ̀rọ, a si mu mi lara le, mo si wipe, Ki oluwa mi ki o ma sọ̀rọ, nitoriti iwọ ti mu mi lara le.


Ṣugbọn nisisiyi mura giri, Iwọ Serubbabeli, li Oluwa wi, ki o si mura giri, Iwọ Joṣua, ọmọ Josedeki, olori alufa; ẹ si mura giri gbogbo ẹnyin enia ilẹ na, li Oluwa wi, ki ẹ si ṣiṣẹ: nitori emi wà pẹlu nyin, li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi.


Bayi li Oluwa awọn ọmọ-ogun wi pe, Jẹ ki ọwọ nyin ki o le, ẹnyin ti ngbọ́ ọ̀rọ wọnyi li ọjọ wọnyi li ẹnu awọn woli ti o wà li ọjọ ti a fi ipilẹ ile Oluwa awọn ọmọ-ogun lelẹ, ki a ba le kọ́ tempili.


Fun awọn wọnyi ni ki a pín ilẹ na ni iní gẹgẹ bi iye orukọ.


Ki ẹnyin ki o si gbà ilẹ na, ki ẹnyin ki o si ma gbé inu rẹ̀: nitoripe mo ti fi ilẹ na fun nyin lati ní i.


Ẹ mã ṣọra, ẹ duro gangan ni igbagbọ́, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹ jẹ alagbara.


Lakotan, ará mi, ẹ jẹ alagbara ninu Oluwa, ati ninu agbara ipá rẹ̀.


Wò o, OLUWA Ọlọrun rẹ ti fi ilẹ na siwaju rẹ: gòke lọ, ki o si gbà a, bi OLUWA, Ọlọrun awọn baba rẹ ti wi fun ọ; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya máṣe fò ọ.


Wò o, mo ti fi ilẹ na siwaju nyin: ẹ wọ̀ ọ lọ ki ẹ si gbà ilẹ na ti OLUWA bura fun awọn baba nyin, fun Abrahamu, fun Isaaki, ati fun Jakobu, lati fi fun wọn ati fun irú-ọmọ wọn lẹhin wọn.


Nitorina ki ẹnyin ki o pa gbogbo ofin mọ́ ti mo filelẹ li aṣẹ fun nyin li oni, ki ẹnyin ki o le lagbara, ki ẹnyin ki o si wọ̀ inu rẹ̀ lọ, ki ẹ si gbà ilẹ na, nibiti ẹnyin nlọ lati gbà a;


O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awọn ọmọ Israeli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ.


NITORINA, iwọ ọmọ mi, jẹ alagbara ninu ore-ọfẹ ti mbẹ ninu Kristi Jesu.


Ẹnikẹni ti o wù ki o ṣe ti o ba tapá si ofin rẹ, ti ki yio si gbọ́ ọ̀rọ rẹ li ohun gbogbo ti iwọ palaṣẹ fun u, pipa li a o pa a: kìki ki iwọ ṣe giri ki o si mu àiya le.


Sá ṣe giri ki o si mu àiya le gidigidi, ki iwọ ki o le kiyesi ati ṣe gẹgẹ bi gbogbo ofin ti Mose iranṣẹ mi ti palaṣẹ fun ọ: má ṣe yà kuro ninu rẹ̀ si ọtún tabi si òsi, ki o le dara fun ọ nibikibi ti iwọ ba lọ.


Emi kò ha paṣẹ fun ọ bi? Ṣe giri ki o si mu àiya le; máṣe bẹ̀ru, bẹ̃ni ki àiya ki o máṣe fò ọ: nitoripe OLUWA Ọlọrun rẹ wà pẹlu rẹ nibikibi ti iwọ ba nlọ.


Joṣua si wi fun wọn pe, Ẹ má ṣe bẹ̀ru, ẹ má si ṣe fòya; ẹ ṣe giri, ki ẹ si mu àiya le: nitoripe bayi li OLUWA yio ṣe si awọn ọtá nyin gbogbo ti ẹnyin mbájà.


Gbogbo awọn ara ilẹ òke lati Lebanoni titi dé Misrefoti-maimu, ani gbogbo awọn ara Sidoni; awọn li emi o lé jade kuro niwaju awọn ọmọ Israeli: kìki ki iwọ ki o fi keké pín i fun Israeli ni ilẹ-iní, gẹgẹ bi mo ti paṣẹ fun ọ.


Joṣua si wi fun awọn ọmọ Israeli pe, Ẹnyin o ti lọra pẹ to lati lọ igbà ilẹ na, ti OLUWA, Ọlọrun awọn baba nyin, ti fi fun nyin?


OLUWA si fun Israeli ni gbogbo ilẹ na, ti o bura lati fi fun awọn baba wọn; nwọn si gbà a, nwọn si ngbé inu rẹ̀.


Nitoriti awọn ọmọ Israeli rìn li ogoji ọdún li aginjù, titi gbogbo iran na, ani awọn ologun, ti o jade ti Egipti wá fi run, nitoriti nwọn kò gbà ohùn OLUWA gbọ́: awọn ti OLUWA bura fun pe, on ki yio jẹ ki wọn ri ilẹ na, ti OLUWA bura fun awọn baba wọn lati fi fun wa, ilẹ ti nṣàn fun warà ati fun oyin.


Ẹ jẹ alagbara, ẹ ṣe bi ọkunrin, ẹnyin Filistini, ki ẹnyin máṣe ẹrú fun awọn Heberu, bi nwọn ti nṣe ẹrú nyin ri: Ẹ ṣe bi ọkunrin, ki ẹ si ja.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan