Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:11 - Bibeli Mimọ

11 Ẹ là ãrin ibudó já, ki ẹ si paṣẹ fun awọn enia, wipe, Ẹ pèse onjẹ; nitoripe ni ijọ́ mẹta oni ẹnyin o gòke Jordani yi, lati lọ gbà ilẹ ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin lati ní.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 “Ẹ lọ káàkiri ibùdó, kí ẹ sì pàṣẹ fún àwọn eniyan náà, pé kí wọn máa pèsè oúnjẹ sílẹ̀, nítorí pé láàrin ọjọ́ mẹta wọn óo la odò Jọdani kọjá láti lọ gba ilẹ̀ tí OLUWA Ọlọrun wọn fún wọn.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 “Ẹ la ibùdó já, kí ẹ sì sọ fún àwọn ènìyàn, ‘Ẹ pèsè oúnjẹ yín sílẹ̀. Ní ìwòyí ọ̀túnla, ẹ̀yin yóò la Jordani yìí kọjá, láti gba ilẹ̀ tí Olúwa Ọlọ́run yín fi fún un yín láti ní.’ ”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:11
9 Iomraidhean Croise  

Tun pada, ki o si wi fun Hesekiah olori awọn enia mi pe, Bayi li Oluwa Ọlọrun Dafidi baba rẹ wi pe, Emi ti gbọ́ adura rẹ, emi si ti ri omije rẹ: kiyesi i, emi o wò ọ sàn: ni ijọ kẹta iwọ o gòke lọ si ile Oluwa.


Ki nwọn ki o si mura dè ijọ́ kẹta: nitori ni ijọ́ kẹta OLUWA yio sọkalẹ sori oke Sinai li oju awọn enia gbogbo.


Lẹhìn ijọ meji, yio tún wa jí: ni ijọ kẹta yio ji wa dide, awa o si wà lãyè niwaju rẹ̀.


Nitoripe ẹnyin o gòke Jordani lati wọle ati lati gbà ilẹ na, ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun nyin, ẹnyin o si gbà a, ẹnyin o si ma gbé inu rẹ̀.


Mo si fun nyin li aṣẹ ni ìgbana, wipe, OLUWA Ọlọrun nyin ti fi ilẹ yi fun nyin lati ní i: ẹnyin o si kọja si ìha keji ni ihamọra ogun niwaju awọn arakunrin nyin, awọn ọmọ Israeli, gbogbo awọn akọni ọkunrin.


GBỌ́, Israeli: iwọ o gòke Jordani li oni, lati wọle lọ ìgba awọn orilẹ-ède ti o tobi ti o si lagbara jù ọ lọ, ilu ti o tobi, ti a mọdi rẹ̀ kàn ọrun,


Nigbana ni Joṣua paṣẹ fun awọn olori awọn enia wipe,


Mose iranṣẹ mi kú; njẹ iwọ, dide, gòke Jordani yi, iwọ, ati gbogbo enia yi, si ilẹ ti mo fi fun wọn, ani fun awọn ọmọ Israeli.


O si ṣe lẹhin ijọ́ mẹta, ni awọn olori là ãrin ibudó já;


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan