Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Joṣua 1:1 - Bibeli Mimọ

1 O si ṣe lẹhin ikú Mose iranṣẹ OLUWA, li OLUWA sọ fun Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, wipe,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

1 Lẹ́yìn ikú Mose, iranṣẹ OLUWA, OLUWA sọ fún Joṣua, ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ Mose pé,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

1 Lẹ́yìn ikú u Mose ìránṣẹ́ Olúwa, Olúwa sọ fún Joṣua ọmọ Nuni, olùrànlọ́wọ́ ọ Mose:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Joṣua 1:1
29 Iomraidhean Croise  

Ati Jehu, ọmọ Nimṣi ni iwọ o fi ororo yàn li ọba lori Israeli: ati Eliṣa, ọmọ Ṣafati, ara Abel-Mehola ni iwọ o fi ororo yan ni woli ni ipò rẹ.


Jehoṣafati si wipe, Kò ha si woli Oluwa kan nihin, ti awa iba ti ọdọ rẹ̀ bère lọwọ Oluwa? Ọkan ninu awọn iranṣẹ ọba Israeli dahùn wipe, Eliṣa, ọmọ Ṣafati ti ntú omi si ọwọ Elijah mbẹ nihinyi.


Gbogbo ijọ enia ninu awọn ti o pada bọ̀ lati oko-ẹrú si pa agọ, nwọn si gbe abẹ awọn agọ na: nitori lati akokò Joṣua ọmọ Nuni wá, titi di ọjọ na awọn ọmọ Israeli kò ṣe bẹ̃. Ayọ̀ nlanla si wà.


Mose si dide, ati Joṣua iranṣẹ rẹ̀: Mose si gòke lọ si oke Ọlọrun.


Joṣua ọmọ Nuni, iranṣẹ Mose, ọkan ninu awọn ọmọkunrin rẹ̀ dahùn, o si wipe, Mose oluwa mi, dá wọn lẹkun.


Mose iranṣẹ mi kò ri bẹ̃, olõtọ ni ninu gbogbo ile mi.


Wọnyi li orukọ awọn ọkunrin na, ti Mose rán lati lọ ṣe amí ilẹ na. Mose si sọ Oṣea ọmọ Nuni ni Joṣua.


Ninu ẹ̀ya Efraimu, Oṣea ọmọ Nuni.


Ẹniti o ba ṣe olõtọ li ohun kikini, o ṣe olõtọ ni pipọ pẹlu: ẹniti o ba si ṣe alaiṣõtọ li ohun kikini, o ṣe alaiṣõtọ li ohun pipo pẹlu.


Ti awọn baba wa ti o tẹle wọn si mu ba Joṣua wá si ilẹ-ini awọn Keferi, ti Ọlọrun lé jade kuro niwaju awọn baba wa, titi di ọjọ Dafidi;


PAULU, iranṣẹ Jesu Kristi, ti a pè lati jẹ aposteli, ti a yà sọ̀tọ fun ihinrere Ọlọrun,


Joṣua ọmọ Nuni, ti ima duro niwaju rẹ, on ni yio dé ibẹ̀: gbà a ni iyanju; nitoripe on ni yio mu Israeli ní i.


O si paṣẹ fun Joṣua ọmọ Nuni, o si wipe, Ṣe giri, ki o si mu àiya le: nitoripe iwọ ni yio mú awọn ọmọ Israeli lọ sinu ilẹ na ti mo bura fun wọn: Emi o si wà pẹlu rẹ.


OLUWA Ọlọrun rẹ, on ni yio rekọja ṣaju rẹ, on ni yio si run orilẹ-ède wọnyi kuro niwaju rẹ, iwọ o si gbà wọn: ati Joṣua, on ni yio gòke ṣaju rẹ, bi OLUWA ti wi.


EYI si ni ire, ti Mose enia Ọlọrun su fun awọn ọmọ Israeli ki o to kú.


Ati ni gbogbo ọwọ́ agbara, ati ni gbogbo ẹ̀ru nla ti Mose fihàn li oju gbogbo Israeli.


Bẹ̃ni Mose iranṣẹ OLUWA kú nibẹ̀ ni ilẹ Moabu, gẹgẹ bi ọ̀rọ OLUWA.


Joṣua ọmọ Nuni si kún fun ẹmi ọgbọ́n; nitoripe Mose ti fi ọwọ́ rẹ̀ lé e lori: awọn ọmọ Israeli si gbà tirẹ̀ gbọ́, nwọn si ṣe bi OLUWA ti paṣẹ fun Mose.


PAULU, iranṣẹ Ọlọrun, ati Aposteli Jesu Kristi, gẹgẹ bi igbagbọ́ awọn ayanfẹ Ọlọrun, ati imọ otitọ ti mbẹ gẹgẹ bi ìwa-bi-Ọlọrun,


JAKỌBU, iranṣẹ Ọlọrun ati ti Jesu Kristi Oluwa, si awọn ẹ̀ya mejila ti o túka kiri, alafia.


Titi OLUWA yio fi fun awọn arakunrin nyin ni isimi, gẹgẹ bi o ti fi fun nyin, ati ti awọn pẹlu yio fi gbà ilẹ na ti OLUWA Ọlọrun nyin fi fun wọn: nigbana li ẹnyin o pada si ilẹ iní nyin, ti Mose iranṣẹ OLUWA fi fun nyin ni ìha ihin Jordani ni ìha ìla-õrùn, ẹnyin o si ní i.


Mose iranṣẹ mi kú; njẹ iwọ, dide, gòke Jordani yi, iwọ, ati gbogbo enia yi, si ilẹ ti mo fi fun wọn, ani fun awọn ọmọ Israeli.


Mose iranṣẹ OLUWA ati awọn ọmọ Israeli kọlù wọn: Mose iranṣẹ OLUWA si fi i fun awọn ọmọ Reubeni ni ilẹ-iní, ati fun awọn ọmọ Gadi, ati fun àbọ ẹ̀ya Manasse.


Emi li ẹniti o mbẹ lãye, ti o si ti kú; si kiyesi i, emi si mbẹ lãye si i titi lai, Amin; mo si ní kọkọrọ ikú ati ti ipo-oku.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan