Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:30 - Bibeli Mimọ

30 Ọkunrin na dahùn o si wi fun wọn pe, Ohun iyanu sá li eyi, pe, ẹnyin kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá, ṣugbọn on sá ti là mi loju.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

30 Ọkunrin náà dá wọn lóhùn pé, “Ohun ìyanu ni èyí! Ẹ kò mọ ibi tí ó ti yọ wá, sibẹ ó là mí lójú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

30 Ọkùnrin náà dáhùn ó sì wí fún wọn pé, “Ohun ìyanu sá à ni èyí, pé ẹ̀yin kò mọ ibi tí ó tí wá, ṣùgbọ́n òun sá à ti là mí lójú.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:30
13 Iomraidhean Croise  

Là mi li oju, ki emi ki o le ma wò ohun iyanu wọnni lati inu ofin rẹ.


Nitorina, Kiye si i, emi o ma ṣe iṣẹ́ iyanu lọ lãrin awọn enia yi, ani iṣẹ iyanu ati ajeji: ọgbọ́n awọn ọlọgbọ́n wọn yio si ṣegbe, oye awọn amoye wọn yio si põra.


Ati li ọjọ na awọn aditi yio si gbọ́ ọ̀rọ iwe nì, awọn afọju yio si riran lati inu owúsuwusù, ati lati inu okunkun.


Nigbana li oju awọn afọju yio là, eti awọn aditi yio si ṣi.


Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi.


Jesu wi fun wọn pe, Ẹnyin ko ti kà a ninu iwe mimọ́ pe, Okuta ti awọn ọmọle kọ̀ silẹ, on na li o si di pàtaki igun ile: eyi ni iṣẹ Oluwa, o si jẹ iyanu li oju wa?


Ẹnu si yà a nitori aigbagbọ́ wọn. O si lọ si gbogbo iletò yiká, o nkọni.


Jesu si dahùn o wi fun wọn pe, Ẹ pada lọ, ẹ ròhin nkan ti ẹnyin ri, ti ẹnyin si gbọ́ fun Johanu: awọn afọju nriran, awọn amukun nrìn ṣaṣa, a sọ awọn adẹtẹ̀ di mimọ́, awọn aditi ngbọran, a njí awọn okú dide, ati fun awọn òtoṣi li a nwasu ihinrere.


Ṣugbọn bi o ti ṣe ọ̀pọlọpọ iṣẹ ami to bayi li oju wọn, nwọn kò gbà a gbọ́;


Jesu dahùn, o si wi fun u pe, Ṣe olukọni ni Israeli ni iwọ iṣe, o kò si mọ̀ nkan wọnyi?


Awa mọ̀ pe Ọlọrun ba Mose sọ̀rọ: ṣugbọn bi o ṣe ti eleyi, awa kò mọ̀ ibiti o gbé ti wá.


Awa mọ̀ pe, Ọlọrun ki igbọ́ ti ẹlẹṣẹ: ṣugbọn bi ẹnikan ba ṣe olufọkansin si Ọlọrun, ti o ba si nṣe ifẹ rẹ̀, on ni igbọ́ tirẹ̀.


Nitori Ọlọrun, ẹniti o wipe ki imọlẹ ki o mọlẹ lati inu òkunkun jade, on li o ti nmọlẹ li ọkàn wa, lati fun wa ni imọlẹ ìmọ ogo Ọlọrun li oju Jesu Kristi.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan