Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:3 - Bibeli Mimọ

3 Jesu dahùn pe, Kì iṣe nitoriti ọkunrin yi dẹṣẹ, tabi awọn obi rẹ̀: ṣugbọn ki a le fi iṣẹ Ọlọrun hàn lara rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Jesu dáhùn pé, “Ati òun ni, ati àwọn òbí rẹ̀ ni, kò sí ẹni tí ó dẹ́ṣẹ̀, ṣugbọn kí iṣẹ́ Ọlọrun lè hàn nípa ìwòsàn rẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:3
16 Iomraidhean Croise  

Kiyesi i, emi mọ̀ iro inu nyin ati arekereke ti ẹnyin fi gba dulumọ si mi.


Inu rẹ̀ si bi si awọn ọ̀rẹ rẹ̀ mẹtẹta, nitoriti nwọn kò ni idahùn, bẹ̃ni nwọn dá Jobu lẹbi.


Bẹ̃li o si ri, lẹhin igbati OLUWA ti sọ ọ̀rọ wọnyi tan fun Jobu, OLUWA si wi fun Elifasi, ara Tema pe, Mo binu si ọ ati si awọn ọrẹ́ rẹ mejeji, nitoripe ẹnyin kò sọ̀rọ niti emi, ohun ti o tọ́ bi Jobu iranṣẹ mi ti sọ.


Awọn afọju nriran, awọn amukun si nrìn, a nwẹ̀ awọn adẹtẹ̀ mọ́, awọn aditi ngbọràn, a njí awọn okú dide, a si nwasu ihinrere fun awọn òtoṣi.


Nigbati Jesu si gbọ́, o wipe, Aisan yi kì iṣe si ikú, ṣugbọn fun ogo Ọlọrun, ki a le yìn Ọmọ Ọlọrun logo nipasẹ rẹ̀.


Jesu wi fun u pe, Emi kò ti wi fun ọ pe, bi iwọ ba gbagbọ́, iwọ o ri ogo Ọlọrun?


Bi awọn alaigbede na si ti ri ẹranko oloró na ti dì mọ́ ọ li ọwọ́, nwọn ba ara wọn sọ pe, Dajudaju apania li ọkunrin yi, ẹniti o yọ ninu okun tan, ṣugbọn ti ẹsan kò si jẹ ki o wà lãye.


Nigbati nwọn si kìlọ fun wọn si i, nwọn jọwọ wọn lọwọ lọ, nigbati nwọn kò ti ri nkan ti nwọn iba fi jẹ wọn ni ìya, nitori awọn enia: nitori gbogbo wọn ni nyìn Ọlọrun logo fun ohun ti a ṣe.


Awa ti mọ̀, a si gbà ifẹ ti Ọlọrun ní si wa gbọ́. Ifẹ ni Ọlọrun; ẹniti o ba si ngbé inu ifẹ o ngbé inu Ọlọrun, ati Ọlọrun ninu rẹ̀.


Nipa eyi li a gbé fi ifẹ Ọlọrun hàn ninu wa, nitoriti Ọlọrun rán Ọmọ bíbi rẹ̀ nikanṣoṣo si aiye, ki awa ki o le yè nipasẹ rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan