Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:22 - Bibeli Mimọ

22 Nkan wọnyi li awọn obi rẹ̀ sọ, nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn Ju: nitori awọn Ju ti fi ohùn ṣọkan pe, bi ẹnikan ba jẹwọ pe, Kristi ni iṣe, nwọn ó yọ ọ kuro ninu sinagogu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

22 Àwọn òbí rẹ̀ fèsì báyìí nítorí wọ́n bẹ̀rù àwọn Juu; nítorí àwọn Juu ti pinnu láti yọ ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ pé Jesu ni Mesaya kúrò ninu àwùjọ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

22 Nǹkan wọ̀nyí ni àwọn òbí rẹ̀ sọ, nítorí tí wọ́n bẹ̀rù àwọn Júù: nítorí àwọn Júù ti fohùn ṣọ̀kan pé bí ẹnìkan bá jẹ́wọ́ pé Kristi ni, wọn ó yọ ọ́ kúrò nínú Sinagọgu.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:22
24 Iomraidhean Croise  

Ibẹ̀ru enia ni imu ikẹkùn wá: ṣugbọn ẹnikẹni ti o gbẹkẹ rẹ̀ le Oluwa li a o gbe leke.


Emi, ani emi ni ẹniti ntù nyin ninu: tani iwọ, ti iwọ o fi bẹ̀ru enia ti yio kú, ati ọmọ enia ti a ṣe bi koriko.


Gbọ́ ti emi, ẹnyin ti o mọ̀ ododo, enia ninu aiya ẹniti ofin mi mbẹ; ẹ máṣe bẹ̀ru ẹgàn awọn enia, ẹ má si ṣe foyà ẹsín wọn.


Ẹ̀ru tani mbà ọ ti o si nfòya, ti o nṣeke, ti iwọ kò si ranti mi tabi ki o kà a si? emi kò ha ti dakẹ ani lati igbãni wá, iwọ kò si bẹ̀ru mi?


Alabukun-fun li ẹnyin, nigbati awọn enia ba korira nyin, ti nwọn ba yà nyin kuro ninu ẹgbẹ wọn, ti nwọn ba gàn nyin, ti nwọn ba ta orukọ nyin nù bi ohun buburu, nitori Ọmọ-enia.


Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?


Nwọn o yọ nyin kuro ninu sinagogu: ani, akokò mbọ̀, ti ẹnikẹni ti o ba pa nyin, yio rò pe on nṣe ìsin fun Ọlọrun.


Lẹhin nkan wọnyi ni Josefu ará Arimatea, ẹniti iṣe ọmọ-ẹhin Jesu, ṣugbọn ni ikọ̀kọ nitori ìbẹru awọn Ju, o bẹ̀ Pilatu ki on ki o le gbé okú Jesu kuro: Pilatu si fun u li aṣẹ. Nitorina li o wá, o si gbé okú Jesu lọ.


Lọjọ kanna, lọjọ ikini ọ̀sẹ nigbati alẹ́ lẹ́, ti a si ti tì ilẹkun ibiti awọn ọmọ-ẹhin gbé pejọ, nitori ìbẹru awọn Ju, bẹni Jesu de, o duro larin, o si wi fun wọn pe, Alafia fun nyin.


Ṣugbọn kò si ẹnikan ti o sọ̀rọ rẹ̀ ni gbangba nitori ìbẹru awọn Ju.


Nitorina awọn Ju kò gbagbọ́ nitori rẹ̀ pe, oju rẹ̀ ti fọ́ ri, ati pe o si tún riran, titi nwọn fi pe awọn obi ẹniti a ti là loju.


Ṣugbọn bi o ti ṣe nriran nisisiyi awa kò mọ̀; tabi ẹniti o la a loju, awa kò mọ̀: ẹniti o gbọ́njú ni iṣe; ẹ bi i lẽre: yio wi fun ara rẹ̀.


Nwọn si dahùn wi fun u pe, Ninu ẹṣẹ li a bi iwọ patapata, iwọ si nkọ́ wa bi? Nwọn si tì i sode.


Jesu gbọ́ pe, nwọn ti tì i sode; nigbati o si ri i, o wipe, Iwọ gbà Ọmọ Ọlọrun gbọ́ bi?


Nigbati nwọn si pè wọn, nwọn paṣẹ fun wọn, ki nwọn máṣe sọ̀rọ rara, bẹni ki nwọn máṣe kọ́ni li orukọ Jesu mọ́.


Ninu awọn iyokù ẹnikan kò daṣà ati dapọ mọ wọn: ṣugbọn enia nkókiki wọn.


Nwọn si tẹ̀ si tirẹ̀: nigbati nwọn si pè awọn aposteli wọle, nwọn lù wọn, nwọn si kìlọ fun wọn pe, ki nwọn ki o máṣe sọ̀rọ li orukọ Jesu mọ́, nwọn si jọwọ wọn lọwọ lọ.


Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan