Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 9:11 - Bibeli Mimọ

11 O dahùn o si wi fun wọn pe, ọkunrin kan ti a npè ni Jesu li o ṣe amọ̀, o si fi kùn mi loju, o si wi fun mi pe, Lọ si adagun Siloamu, ki o si wẹ̀: emi si lọ, mo wẹ̀, mo si riran.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

11 Ó dá wọn lóhùn pé, “Ọkunrin tí wọn ń pè ní Jesu ni ó po amọ̀, tí ó fi lẹ̀ mí lójú, tí ó sọ fún mi pé kí n lọ bọ́jú ní adágún Siloamu. Mo lọ, mo bọ́jú, mo sì ríran.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

11 Ó dáhùn ó sì wí fún un pé, “Ọkùnrin kan tí a ń pè ní Jesu ni ó ṣe amọ̀, ó sì fi kun ojú mí, ó sì wí fún mi pé, ‘Lọ sí adágún Siloamu, kí o sì wẹ̀,’ èmi sì lọ, mo wẹ̀, mo sì ríran.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 9:11
6 Iomraidhean Croise  

Nwọn si bi Baruku wipe, Sọ fun wa nisisiyi, bawo ni iwọ ṣe kọ gbogbo ọ̀rọ wọnyi lati ẹnu rẹ̀?


Tabi awọn mejidilogun, ti ile-iṣọ ni Siloamu wólu, ti o si pa wọn, ẹnyin ṣebi nwọn ṣe ẹlẹṣẹ jù gbogbo awọn enia ti mbẹ̀ ni Jerusalemu lọ?


Nitorina ni nwọn wi fun u pe, Njẹ oju rẹ ti ṣe là?


Nwọn si wi fun u pe, On na ha dà? O wipe, emi kò mọ̀.


O da wọn lohùn wipe, Emi ti sọ fun nyin na, ẹnyin ko si gbọ́: nitori kini ẹnyin ṣe nfẹ tún gbọ́? ẹnyin pẹlu nfẹ ṣe ọmọ-ẹhin rẹ̀ bi?


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan