Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:54 - Bibeli Mimọ

54 Jesu dahùn wipe, Bi mo ba nyìn ara mi li ogo, ogo mi kò jẹ nkan: Baba mi ni ẹniti nyìn mi li ogo, ẹniti ẹnyin wipe, Ọlọrun nyin ni iṣe:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

54 Jesu dáhùn pé, “Bí mo bá bu ọlá fún ara mi, òfo ni ọlá mi. Baba mi ni ó bu ọlá fún mi, òun ni ẹ̀yin ń pè ní Ọlọrun yín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

54 Jesu dáhùn wí pé, “Bí mo bá yin ara mi lógo, ògo mi kò jẹ́ nǹkan; Baba mi ni ẹni tí ń yìn mí lógo, ẹni tí ẹ̀yin wí pé, Ọlọ́run yín ní i ṣe:

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:54
28 Iomraidhean Croise  

Kò dara lati mã jẹ oyin pupọ: bẹni kò dara lati mã wa ogo ara ẹni.


Ẹ gbọ́ ọ̀rọ Oluwa, ẹnyin ti o nwarìri si ọ̀rọ rẹ̀; Awọn arakunrin nyin ti nwọn korira nyin, ti nwọn ta nyin nù nitori orukọ mi, wipe, Jẹ ki a fi ogo fun Oluwa: ṣugbọn on o fi ara hàn fun ayọ̀ nyin, oju yio si tì awọn na.


Nigbana ni Ọlọrun wipe, Pè orukọ rẹ̀ ni Loammi; nitori ẹnyin kì iṣe enia mi, emi kì yio si ṣe Ọlọrun nyin.


NKAN wọnyi ni Jesu sọ, o si gbé oju rẹ̀ soke ọrun, o si wipe, Baba, wakati na de: yìn Ọmọ rẹ logo, ki Ọmọ rẹ ki o le yìn ọ logo pẹlu:


Njẹ nisisiyi, Baba, ṣe mi logo pẹlu ara rẹ, ogo ti mo ti ní pẹlu rẹ ki aiye ki o to wà.


Akọṣe iṣẹ àmi yi ni Jesu ṣe ni Kana ti Galili, o si fi ogo rẹ̀ hàn; awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ si gbà a gbọ́.


Emi kò gbà ogo lọdọ enia.


Ẹniti nsọ̀ ti ara rẹ̀ nwá ogo ara rẹ̀: ṣugbọn ẹniti nwá ogo ẹniti o rán a, on li olõtọ, kò si si aiṣododo ninu rẹ̀.


(Ṣugbọn o sọ eyi niti Ẹmí, ti awọn ti o gbà a gbọ́ mbọ̀wá gbà: nitori a kò ti ifi Ẹmí Mimọ́ funni; nitoriti a kò ti iṣe Jesu logo.)


Ẹnyin nṣe iṣẹ baba nyin. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, A ko bí wa nipa panṣaga: a ni Baba kan, eyini li Ọlọrun.


Emi kò wá ogo ara mi: ẹnikan mbẹ ti o nwà a ti o si nṣe idajọ.


Ọlọrun Abrahamu, ati ti Isaaki, ati ti Jakọbu, Ọlọrun awọn baba wa, on li o ti yìn Jesu Ọmọ rẹ̀ logo; ẹniti ẹnyin ti fi le wọn lọwọ, ti ẹnyin si sẹ́ niwaju Pilatu, nigbati o ti pinnu rẹ̀ lati da a silẹ.


Nitoripe kì iṣe ẹniti nyìn ara rẹ̀ li o yanju, bikoṣe ẹniti Oluwa yìn.


Awọn ẹniti a fihàn fun, pe kì iṣe fun awọn tikarawọn, bikoṣe fun awa ni nwọn ṣe iranṣẹ ohun wọnni, ti a ròhin fun nyin nisisiyi, lati ọdọ awọn ti o ti nwãsu ihinrere fun nyin pẹlu Ẹmí Mimọ́ ti a rán lati ọrun wá; ohun ti awọn angẹli nfẹ lati wò.


Ani ẹnyin ti o ti ipasẹ rẹ̀ gbà Ọlọrun gbọ́, ẹniti o jí i dide kuro ninu okú, ti o si fi ogo fun u; ki igbagbọ́ ati ireti nyin ki o le wà lọdọ Ọlọrun.


Nitoriti o gbà ọlá on ogo lati ọdọ Ọlọrun Baba, nigbati irú ohùn nì fọ̀ si i lati inu ogo nla na wá pe, Eyi li ayanfẹ Ọmọ mi, ẹniti inu mi dùn si jọjọ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan