Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:52 - Bibeli Mimọ

52 Awọn Ju wi fun u pe, Nigbayi ni awa mọ̀ pe iwọ li ẹmi èṣu. Abrahamu kú, ati awọn woli; iwọ si wipe, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, kì yio tọ́ ikú wò lailai.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

52 Àwọn Juu wá sọ fún un pé, “A wá mọ̀ dájú pé o ní ẹ̀mí èṣù wàyí! Abrahamu kú. Àwọn wolii kú. Ìwọ wá ń sọ pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kò ní tọ́ ikú wò laelae.’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

52 Àwọn Júù wí fún un pé, “Nígbà yìí ni àwa mọ̀ pé ìwọ ní ẹ̀mí èṣù. Abrahamu kú, àti àwọn wòlíì; ìwọ sì wí pé, ‘Bí ẹnìkan bá pa ọ̀rọ̀ mi mọ́, kì yóò tọ́ ikú wò láéláé’

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:52
14 Iomraidhean Croise  

Nitori Johanu wá, kò jẹ, bẹ̃ni kò mu, nwọn si wipe, o li ẹmi èṣu.


Eyi si li ẹrí Johanu, nigbati awọn Ju rán awọn alufã ati awọn ọmọ Lefi lati Jerusalemu wá lati bi i lẽre pe, Tani iwọ ṣe?


Jesu dahùn o si wi fun u pe, Bi ẹnikan ba fẹràn mi, yio pa ọ̀rọ mi mọ́: Baba mi yio si fẹran rẹ̀, awa o si tọ̀ ọ wá, a o si ṣe ibugbe wa pẹlu rẹ̀.


Ẹ ranti ọ̀rọ ti mo ti sọ fun nyin pe, Ọmọ-ọdọ kò tobi jù oluwa rẹ̀ lọ. Bi nwọn ba ti ṣe inunibini si mi, nwọn ó ṣe inunibini si nyin pẹlu: bi nwọn ba ti pa ọ̀rọ mi mọ́, nwọn ó si pa ti nyin mọ́ pẹlu.


Emi ti fi orukọ rẹ hàn fun awọn enia ti iwọ ti fifun mi lati inu aiye wá: tirẹ ni nwọn ti jẹ ri, iwọ si ti fi wọn fun mi; nwọn si ti pa ọ̀rọ rẹ mọ́.


Ijọ enia dahùn nwọn si wipe, Iwọ li ẹmi èṣu: tani nwá ọ̀na lati pa ọ?


Nitorina awọn Ju wipe, On o ha pa ara rẹ̀ bi? nitoriti o wipe, Ibiti emi gbé nlọ, ẹnyin kì ó le wá.


Awọn Ju dahùn nwọn si wi fun u pe, Awa kò wi nitõtọ pe, ara Samaria ni iwọ iṣe, ati pe iwọ li ẹmi èṣu?


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Bi ẹnikan ba pa ọ̀rọ mi mọ́, ki yio ri ikú lailai.


Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́.


Nitorina nwọn pè ọkunrin afọju na lẹ̃keji, nwọn si wi fun u pe, Fi ogo fun Ọlọrun: awa mọ̀ pe ẹlẹṣẹ li ọkunrin yi iṣe.


Gbogbo awọn wọnyi li o kú ni igbagbọ́, lai ri ileri wọnni gbà, ṣugbọn ti nwọn ri wọn li òkere rere, ti nwọn si gbá wọn mú, ti nwọn si jẹwọ pe alejò ati atipò li awọn lori ilẹ aiye.


Awa ri ẹniti a dá rẹlẹ̀ diẹ jù awọn angẹli lọ, ani Jesu, ẹniti a fi ogo ati ọlá dé li ade nitori ijiya ikú; ki o le tọ́ iku wò fun olukuluku enia nipa õre-ọfẹ Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan