Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:44 - Bibeli Mimọ

44 Ti eṣu baba nyin li ẹnyin iṣe, ifẹkufẹ baba nyin li ẹ si nfẹ ṣe. Apania li on iṣe lati atetekọṣe, ko si duro ni otitọ; nitoriti kò si otitọ ninu rẹ̀. Nigbati o ba nṣeke, ninu ohun tirẹ̀ li o nsọ, nitori eke ni, ati baba eke.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

44 Láti ọ̀dọ̀ èṣù baba yín, ni ẹ ti wá. Ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ ń fẹ́ ṣe. Òun ní tirẹ̀, apànìyàn ni láti ìbẹ̀rẹ̀, ara rẹ̀ kọ òtítọ́ nítorí kò sí òtítọ́ ninu rẹ̀. Nígbà tí ó bá sọ̀rọ̀, irọ́ ni ó ń pa. Ọ̀rọ̀ ti ara rẹ̀ ní ń sọ. Òpùrọ́ ni, òun sì ni baba irọ́.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

44 Ti èṣù baba yin ni ẹ̀yin jẹ́, ìfẹ́kúfẹ̀ẹ́ baba yín ni ẹ sì ń fẹ́ ṣe. Apànìyàn ni òun jẹ́ láti àtètèkọ́ṣe, kò sì dúró nínú òtítọ́; nítorí tí kò sí òtítọ́ nínú rẹ̀. Nígbà tí ó bá ń ṣèké, nínú ohun tirẹ̀ ni ó ń sọ nítorí èké ni, àti baba èké.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:44
41 Iomraidhean Croise  

Emi o si fi ọta sãrin iwọ ati obinrin na, ati sãrin irú-ọmọ rẹ ati irú-ọmọ rẹ̀: on o fọ́ ọ li ori, iwọ o si pa a ni gigĩsẹ.


Oluwa si wi fun u pe, Bawo? O si wipe, Emi o jade lọ, emi o si di ẹmi-eke li ẹnu gbogbo awọn woli rẹ̀. On si wipe, Iwọ o tàn a, iwọ o si bori pẹlu: jade lọ, ki o si ṣe bẹ̃.


SATANI si duro tì Israeli, o si tì Dafidi lati ka iye Israeli.


Njẹ nawọ rẹ nisisiyi, ki o si fi tọ́ ohun gbogbo ti o ni; bi kì yio si bọhùn li oju rẹ.


Ẹnyin ọmọ paramọlẹ, ẹnyin ti iṣe enia buburu yio ti ṣe le sọ̀rọ rere? nitori ninu ọ̀pọlọpọ ohun inu li ẹnu isọ.


Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo ọ̀ran igbọ́, oju wọn ni nwọn si dì; nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi àiya wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki emi ki o má ba mu wọn larada.


Oko li aiye; irugbin rere li awọn ọmọ ijọba; èpo si li awọn ọmọ ẹni buburu ni;


Jesu da wọn lohùn pe, Ẹnyin mejila kọ́ ni mo yàn, ọkan ninu nyin kò ha si yà Èṣu?


Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi.


Ohun ti emi ti ri lọdọ Baba ni mo nsọ: ẹnyin pẹlu si nṣe eyi ti ẹnyin ti gbọ lati ọdọ baba nyin.


Ẹnyin nṣe iṣẹ baba nyin. Nigbana ni nwọn wi fun u pe, A ko bí wa nipa panṣaga: a ni Baba kan, eyini li Ọlọrun.


Ẹ kò si mọ̀ ọ; ṣugbọn emi mọ̀ ọ: bi mo ba si wipe, emi kò mọ̀ ọ, emi ó di eke gẹgẹ bi ẹnyin: ṣugbọn emi mọ̀ ọ, mo si pa ọ̀rọ rẹ̀ mọ́.


Iwọ ti o kún fun arekereke gbogbo, ati fun iwà-ìka gbogbo, iwọ ọmọ Eṣu, iwọ ọta ododo gbogbo, iwọ kì yio ha dẹkun ati ma yi ọna titọ́ Oluwa po?


Awọn Ju pẹlu si fi ohùn si i, wipe, bẹ̃ni nkan wọnyi ri.


Ṣugbọn Peteru wipe, Anania, Ẽṣe ti Satani fi kún ọ li ọkàn lati ṣeke si Ẹmí Mimọ́, ti iwọ si fi yàn apakan pamọ́ ninu owo ilẹ na?


Ṣugbọn ẹru mba mi pe, li ohunkohun, gẹgẹ bi ejò ti tàn Efa jẹ nipasẹ arekereke rẹ̀, ki a maṣe mu ero-ọkàn nyin bajẹ kuro ninu inu kan ati iwa mimọ́ nyin si Kristi.


Ẹ mã wà li airekọja, ẹ mã ṣọra; nitori Èṣu, ọtá nyin, bi kiniun ti nke ramuramu, o nrìn kãkiri, o nwá ẹniti yio pajẹ kiri:


Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ;


Bi awa ba wipe awa kò li ẹ̀ṣẹ, awa tàn ara wa jẹ, otitọ kò si si ninu wa.


Emi kò kọwe si nyin nitoripe ẹnyin kò mọ̀ otitọ, ṣugbọn nitoriti ẹnyin mọ̀ ọ, ati pe kò si eke ninu otitọ.


Ẹniti o ba wipe, emi mọ̀ ọ, ti kò si pa ofin rẹ̀ mọ́, eke ni, otitọ kò si si ninu rẹ̀.


Ki iṣe bi Kaini, ti jẹ́ ti ẹni buburu nì, ti o si pa arakunrin rẹ̀. Nitori kili o si ṣe pa a? Nitoriti iṣẹ on jẹ buburu, ti arakunrin rẹ̀ si jẹ ododo.


Ẹnikẹni ti o ba korira arakunrin rẹ̀ apania ni: ẹnyin si mọ̀ pe kò si apania ti o ni ìye ainipẹkun lati mã gbé inu rẹ̀.


Ati awọn angẹli ti kò tọju ipò ọla wọn ṣugbọn ti nwọn fi ipò wọn silẹ, awọn ni o pamọ́ ninu ẹ̀wọn ainipẹkun nisalẹ òkunkun de idajọ ọjọ nla nì.


A si lé dragoni nla na jade, ejò lailai nì, ti a npè ni Èṣu, ati Satani, ti ntàn gbogbo aiye jẹ, a si lé e jù si ilẹ aiye, a si le awọn angẹli rẹ̀ jade pẹlu rẹ̀.


O si ntàn awọn ti ngbe ori ilẹ aiye jẹ nipa awọn ohun iyanu ti a fi fun u lati ṣe niwaju ẹranko na; o nwi fun awọn ti ngbe ori ilẹ aiye lati ya aworan fun ẹranko na ti o ti gbà ọgbẹ idà, ti o si yè.


Máṣe bẹ̀ru ohunkohun tì iwọ mbọ̀ wá jiya rẹ̀: kiyesi i, Èṣu yio gbé ninu nyin jù sinu tubu, ki a le dán nyin wò; ẹnyin o si ni ipọnju ni ijọ mẹwa: iwọ sa ṣe olõtọ de oju ikú, emi ó si fi ade ìye fun ọ.


Ṣugbọn awọn ojo, ati alaigbagbọ́, ati ẹni irira, ati apania, ati àgbèrè, ati oṣó, ati abọriṣa, ati awọn eke gbogbo, ni yio ní ipa tiwọn ninu adagun ti nfi iná ati sulfuru jò: eyi ti iṣe ikú keji.


Nitori li ode ni awọn ajá gbé wà, ati awọn oṣó, ati awọn àgbere, ati awọn apania, ati awọn abọriṣa, ati olukuluku ẹniti o fẹran eke ti o si nhuwa eke.


Nwọn ni angẹli ọgbun na bi ọba lori wọn, orukọ rẹ̀ li ede Heberu ni Abaddoni, ati li ède Griki orukọ rẹ̀ amã jẹ Apollioni.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan