Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:43 - Bibeli Mimọ

43 Ẽtiṣe ti ède mi kò fi yé nyin? nitori ẹ ko le gbọ́ ọ̀rọ mi ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

43 Nítorí kí ni ohun tí mò ń sọ fun yín kò fi ye yín? Ìdí rẹ̀ ni pé ara yín kò lè gba ọ̀rọ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

43 Èéṣe tí èdè mi kò fi yé yín? Nítorí ẹ kò lè gbọ́ ọ̀rọ̀ mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:43
18 Iomraidhean Croise  

Oye idajọ kò ye enia buburu: ṣugbọn awọn ti nṣe afẹri Oluwa moye ohun gbogbo.


Nwọn kò mọ̀, oye ko si ye wọn: nitori o dí wọn li oju, ki nwọn ki o má le ri; ati aiya wọn, ki oye ki o má le ye wọn.


On si wipe, Lọ, ki o si wi fun awọn enia yi, Ni gbigbọ́, ẹ gbọ́, ṣugbọn oye ki yio ye nyin; ni riri, ẹ ri, ṣugbọn ẹnyin ki yio si mọ̀ oye.


Tani emi o sọ fun, ti emi o kilọ fun ti nwọn o si gbọ́? sa wò o, eti wọn jẹ alaikọla, nwọn kò si le fi iye si i: sa wò o, ọ̀rọ Oluwa di ẹ̀gan si wọn, nwọn kò ni inu didùn ninu rẹ̀.


Tali o gbọ́n, ti o lè moye nkan wọnyi? tali o li oye, ti o le mọ̀ wọn? nitori ọ̀na Oluwa tọ́, awọn olododo yio si ma rìn ninu wọn: ṣugbọn awọn alarekọja ni yio ṣubu sinu wọn.


Ṣugbọn nwọn kò mọ̀ erò Oluwa, bẹ̃ni oye ìmọ rẹ̀ kò ye wọn: nitori on o kó wọn jọ bi ití sinu ipaka.


Nitoriti àiya awọn enia yi sebọ, etí wọn si wuwo ọ̀ran igbọ́, oju wọn ni nwọn si dì; nitori ki nwọn ki o má ba fi oju wọn ri, ki nwọn ki o má ba fi etí wọn gbọ́, ki nwọn ki o má ba fi àiya wọn mọ̀, ki nwọn ki o má ba yipada, ki emi ki o má ba mu wọn larada.


Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Wakati na mbọ̀, o si de tan nisisiyi, nigbati awọn okú yio gbọ́ ohùn Ọmọ Ọlọrun: awọn ti o ba gbọ yio si yè.


Emi wá li orukọ Baba mi, ẹnyin kò si gbà mi: bi ẹlomiran ba wá li orukọ ara rẹ̀, on li ẹnyin ó gbà.


Nitorina nigbati ọ̀pọ awọn ọmọ-ẹhin rẹ̀ gbọ́ eyi, nwọn wipe, ọ̀rọ ti o le li eyi; tani le gbọ́ ọ?


Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi.


Kò yé wọn pe, ti Baba li o nsọ fun wọn.


Nwọn da a lohùn wipe, Irú-ọmọ Abrahamu li awa iṣe, awa kò si ṣe ẹrú fun ẹnikẹni ri lai: iwọ ha ṣe wipe, Ẹ o di omnira?


Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Abrahamu ni baba wa. Jesu wi fun wọn pe, Ibaṣepe ọmọ Abrahamu li ẹnyin iṣe, ẹnyin iba ṣe iṣẹ Abrahamu.


Ẹnyin ọlọrùn-lile ati alaikọla àiya on etí, nigba-gbogbo li ẹnyin ima dèna Ẹmí Mimọ́: gẹgẹ bi awọn baba nyin, bẹ̃li ẹnyin.


Kò si ẹniti oyé yé, kò si ẹniti o nwá Ọlọrun.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan