Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:34 - Bibeli Mimọ

34 Jesu da wọn lohun pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun nyin, Ẹnikẹni ti o ba ndẹṣẹ, on li ẹrú ẹ̀ṣẹ.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Mo fẹ́ kí ẹ mọ̀ dájúdájú pé ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

34 Jesu dá wọn lóhùn pé, “Lóòótọ́, lóòótọ́ ni mo wí fún yín, Ẹnikẹ́ni tí ó bá ń dẹ́ṣẹ̀, ẹrú ẹ̀ṣẹ̀ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:34
16 Iomraidhean Croise  

Ṣugbọn kò si ẹnikan bi Ahabu ti o tà ara rẹ̀ lati ṣiṣẹ buburu niwaju Oluwa, ẹniti Jesebeli aya rẹ̀ ntì.


Ẹ̀ṣẹ ẹni-buburu ni yio mu ontikararẹ̀, okùn ẹ̀ṣẹ ara rẹ̀ yio si dì i mu.


Lõtọ ni mo sá wi fun nyin, Titi ọrun on aiye yio fi kọja lọ, ohun kikini kan ninu ofin kì yio kọja, bi o ti wù ki o ri, titi gbogbo rẹ̀ yio fi ṣẹ.


Jesu dahùn o si wi fun u pe, Lõtọ, lõtọ ni mo wi fun ọ, Bikoṣepe a tún enia bí, on kò le ri ijọba Ọlọrun.


Nitoriti mo woye pe, iwọ wà ninu ikorò orõro, ati ni ìde ẹ̀ṣẹ.


Nitorina ẹ maṣe jẹ ki ẹ̀ṣẹ ki o jọba ninu ara kiku nyin, ti ẹ o fi mã gbọ ti ifẹkufẹ rẹ̀;


Ẹnyin kò mọ̀ pe, ẹniti ẹnyin ba jọwọ ara nyin lọwọ fun bi ẹrú lati mã gbọ́ tirẹ̀, ẹrú ẹniti ẹnyin ba gbọ tirẹ̀ li ẹnyin iṣe; ibãṣe ti ẹ̀ṣẹ sinu ikú, tabi ti igbọran si ododo?


Nitori awa mọ eyi pe, a kàn ogbologbo ọkunrin wa mọ agbelebu pẹlu rẹ̀, ki a le pa ara ẹ̀ṣẹ run, ki awa maṣe sìn ẹ̀ṣẹ mọ́.


Nitori awa mọ̀ pe ohun ẹmí li ofin: ṣugbọn ẹni ti ara li emi, ti a ti tà sabẹ ofin.


Mo dupẹ lọwọ Ọlọrun nipasẹ Jesu Kristi Oluwa wa. Njẹ nitorina emi tikarami nfi inu jọsin fun ofin Ọlọrun; ṣugbọn mo nfi ara jọsin fun ofin ẹ̀ṣẹ.


Nitori a ó sọ ẹda tikalarẹ di omnira kuro ninu ẹrú idibajẹ, si omnira ogo awọn ọmọ Ọlọrun.


Ninu eyiti ẹnyin ti nrin rí gẹgẹ bi ipa ti aiye yi, gẹgẹ bi alaṣẹ agbara oju ọrun, ẹmí ti nṣiṣẹ nisisiyi ninu awọn ọmọ alaigbọran:


Nitori awa pẹlu ti jẹ were nigbakan rí, alaigbọran aṣako, ẹniti nsin onirũru ifẹkufẹ ati adùn aiye, a wà ninu arankàn ati ilara, a jẹ ẹni irira, a si nkorira awọn ọmọnikeji wa.


Nwọn a mã ṣe ileri omnira fun wọn, nigbati awọn pãpã jẹ ẹrú idibajẹ́: nitori ẹniti o ba ṣẹgun ẹni, on na ni isi sọ ni di ẹrú.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan