Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:3 - Bibeli Mimọ

3 Awọn akọwe ati awọn Farisi si mu obinrin kan wá sọdọ rẹ̀, ti a mu ninu panṣaga; nigbati nwọn si mu u duro larin,

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

3 Àwọn amòfin ati àwọn Farisi mú obinrin kan wá, tí wọ́n ká mọ́ ibi tí ó ti ń ṣe àgbèrè. Wọ́n ní kí ó dúró láàrin wọn;

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

3 Àwọn akọ̀wé àti àwọn Farisi sì mú obìnrin kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀, tí a mú nínú ṣíṣe panṣágà; wọ́n sì mú un dúró láàrín.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:3
10 Iomraidhean Croise  

Emi o si dá ọ lẹjọ, gẹgẹ bi a ti da awọn obinrin lẹjọ ti o ba igbeyawo jẹ ti nwọn si ta ẹjẹ silẹ; emi o si fi ẹjẹ fun ọ, ni irúnu ati ni ijowu.


Ati awọn ọkunrin olododo, nwọn o ṣe idajọ wọn, bi a ti iṣe idajọ awọn àgbere obinrin, ati bi a ti iṣe idajọ awọn obinrin ti o ta ẹjẹ silẹ; nitoripe àgbere ni nwọn, ẹjẹ si wà lọwọ wọn.


Awọn ti o ri i ti nṣẹ́ igi mú u tọ̀ Mose ati Aaroni wá, ati gbogbo ijọ.


Nigbati o si pè gbogbo awọn olori alufa ati awọn akọwe awọn enia jọ, o bi wọn lẽre ibiti a o gbé bí Kristi.


O si tún pada wá si tẹmpili ni kutukutu owurọ̀, gbogbo enia si wá sọdọ rẹ̀; o si joko, o nkọ́ wọn.


Nwọn wi fun u pe, Olukọni, a mu obinrin yi ninu panṣaga, ninu ṣiṣe e pãpã.


Nigbati nwọn gbọ eyi, nwọn si jade lọ lọkọ̃kan, bẹrẹ lati ọdọ awọn àgba titi de awọn ti o kẹhin; a si fi Jesu nikan silẹ, ati obinrin na lãrin, nibiti o ti wà.


Nwọn mu ẹniti oju rẹ̀ ti fọ́ ri wá sọdọ awọn Farisi.


Nigbati nwọn si mu wọn duro li ãrin, nwọn bère pe, Agbara tabi orukọ wo li ẹnyin fi ṣe eyi?


Njẹ bi o ba ni ọkọ miran nigbati ọkọ rẹ̀ wà lãye, panṣaga li a o pè e: ṣugbọn bi ọkọ rẹ̀ ba kú, o bọ lọwọ ofin na; ki yio si jẹ panṣaga bi o ba ni ọkọ miran.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan