Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:16 - Bibeli Mimọ

16 Ṣugbọn bi emi ba si ṣe idajo, otitọ ni idajọ mi: nitori emi nikan kọ́, ṣugbọn emi ati Baba ti o rán mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

16 Bí mo bá tilẹ̀ ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni ìdájọ́ mi, nítorí kì í ṣe èmi nìkan ni mò ń ṣe ìdájọ́, èmi ati Baba tí ó rán mi níṣẹ́ ni.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

16 Ṣùgbọ́n bí èmi bá sì ṣe ìdájọ́, òtítọ́ ni: nítorí èmi nìkan kọ́, ṣùgbọ́n èmi àti Baba tí ó rán mi.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:16
15 Iomraidhean Croise  

Niwaju Oluwa; nitori ti mbọwa iṣe idajọ aiye: pẹlu ododo ni yio fi ṣe idajọ aiye, ati awọn orilẹ-ède li aiṣègbe.


Agbara ọba fẹ idajọ pẹlu, iwọ fi idi aiṣegbe mulẹ; iwọ nṣe idajọ ati ododo ni Jakobu.


Ijọba yio bi si i, alafia ki yio ni ipẹkun: lori itẹ Dafidi, ati lori ijọba rẹ̀, lati ma tọ́ ọ, ati lati fi idi rẹ̀ mulẹ, nipa idajọ, ati ododo lati isisiyi lọ, ani titi lai. Itara Oluwa awọn ọmọ-ogun yio ṣe eyi.


Yọ̀ gidigidi, iwọ ọmọbinrin Sioni; ho, Iwọ ọmọbinrin Jerusalemu: kiye si i, Ọba rẹ mbọ̀wá sọdọ rẹ: ododo li on, o si ni igbalà; o ni irẹ̀lẹ, o si ngùn kẹtẹkẹtẹ, ani ọmọ kẹtẹkẹtẹ.


Kiyesi i, wakati mbọ̀, ani o de tan nisisiyi, ti a o fọ́n nyin ká kiri, olukuluku si ile rẹ̀; ẹ ó si fi emi nikan silẹ: ṣugbọn kì yio si ṣe emi nikan, nitoriti Baba mbẹ pẹlu mi.


Ẹniti o rán mi si mbẹ pẹlu mi: kò jọwọ emi nikan si; nitoriti emi nṣe ohun ti o wù u nigbagbogbo.


Niwọnbi o ti da ọjọ kan, ninu eyi ti yio ṣe idajọ aiye li ododo, nipasẹ ọkunrin na ti o ti yàn, nigbati o ti fi ohun idaniloju fun gbogbo enia, niti o jí i dide kuro ninu okú.


Mo si ri ọrun ṣí silẹ, si wo o, ẹṣin funfun kan; ẹniti o si joko lori rẹ̀ ni a npe ni Olododo ati Olõtọ, ninu ododo li o si nṣe idajọ, ti o si njagun.


Ṣugbọn Oluwa wi fun Samueli pe, máṣe wo oju rẹ̀, tabi giga rẹ̀; nitoripe emi kọ̀ ọ: nitoriti Oluwa kì iwò bi enia ti nwò; enia a ma wò oju, Oluwa a ma wò ọkàn.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan