Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 8:12 - Bibeli Mimọ

12 Jesu si tun sọ fun wọn pe, Emi ni imọlẹ aiye; ẹniti o ba tọ̀ mi lẹhin kì yio rìn ninu òkunkun, ṣugbọn yio ni imọlẹ ìye.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

12 Jesu tún wí fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé. Ẹni tí ó bá ń tẹ̀lé mi kò ní rìn ninu òkùnkùn, ṣugbọn yóo wá sinu ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

12 Jesu sì tún sọ fún wọn pé, “Èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé, ẹni tí ó bá tọ̀ mí lẹ́yìn kì yóò rìn nínú òkùnkùn, ṣùgbọ́n yóò ní ìmọ́lẹ̀ ìyè.”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 8:12
31 Iomraidhean Croise  

O ti gba ọkàn mi kuro ninu ilọ sinu ihò, ẹmi mi yio si ri imọlẹ!


Nitori iwọ ni yio tàn fitila mi: Oluwa Ọlọrun mi yio tàn imọlẹ si òkunkun mi.


Ọkàn yio lọ si ọdọ iran awọn baba rẹ̀; nwọn kì yio ri imọlẹ lailai.


A funrugbin imọlẹ fun olododo, ati inu didùn fun alaiya diduro.


O si wipe, O ṣe ohun kekere ki iwọ ṣe iranṣẹ mi, lati gbe awọn ẹyà Jakobu dide, ati lati mu awọn ipamọ Israeli pada: emi o si fi ọ ṣe imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le ṣe igbala mi titi de opin aiye.


Tani ninu nyin ti o bẹ̀ru Oluwa, ti o gba ohùn iranṣẹ rẹ̀ gbọ́, ti nrìn ninu okùnkun, ti kò si ni imọlẹ? jẹ ki on gbẹkẹ̀le orukọ Oluwa, ki o si fi ẹ̀hìn tì Ọlọrun rẹ̀.


Awọn enia ti nrin li okùnkun ri imọlẹ nla: awọn ti ngbe ilẹ ojiji ikú, lara wọn ni imọlẹ mọ́ si.


Nigbana li awa o mọ̀, bi a ba tẹramọ́ ati mọ̀ Oluwa: ati pèse ijadelọ rẹ̀ bi owùrọ: on o si tọ̀ wa wá bi ojò: bi arọ̀kuro ati akọrọ̀ òjo si ilẹ.


Ṣugbọn Õrùn ododo yio là, ti on ti imularada ni iyẹ́-apá rẹ̀, fun ẹnyin ti o bẹ̀ru orukọ mi; ẹnyin o si jade lọ, ẹnyin o si ma dagba bi awọn ẹgbọrọ malu inu agbo.


Ẹnyin ni imọlẹ aiye. Ilu ti a tẹ̀do lori òke ko le farasin.


Imọlẹ lati mọ́ si awọn Keferi, ati ogo Israeli enia rẹ.


Nigbana ni Jesu wi fun wọn pe, Nigba diẹ si i ni imọlẹ wà lãrin nyin. Ẹ mã rìn nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ki òkunkun máṣe ba le nyin: ẹniti o ba si nrìn li òkunkun kò mọ̀ ibiti on gbé nlọ.


Nigbati ẹnyin ni imọlẹ, ẹ gbà imọlẹ gbọ́, ki ẹ le jẹ ọmọ imọlẹ. Nkan wọnyi ni Jesu sọ, o si jade lọ, o fi ara pamọ́ fun wọn.


Emi ni imọlẹ ti o wá si aiye, ki ẹnikẹni ti o ba gbà mi gbọ́ ki o máṣe wà li òkunkun.


Jesu wi fun u pe, Emi li ọ̀na, ati otitọ, ati iye: kò si ẹnikẹni ti o le wá sọdọ Baba, bikoṣe nipasẹ mi.


Eyi ni idajọ na pe, imọlẹ wá si aiye, awọn enia si fẹ òkunkun jù imọlẹ lọ, nitoriti iṣẹ wọn buru.


Bi ẹnikẹni ba fẹ lati ṣe ifẹ rẹ̀, yio mọ̀ niti ẹkọ́ na, bi iba ṣe ti Ọlọrun, tabi bi emi ba nsọ ti ara mi.


Niwọn igba ti mo wà li aiye, emi ni imọlẹ aiye.


Bẹ̃li Oluwa sá ti paṣẹ fun wa pe, Mo ti gbé ọ kalẹ fun imọlẹ awọn Keferi, ki iwọ ki o le jẹ fun igbala titi de opin aiye.


Pe, Kristi yio jìya, ati pe nipa ajinde rẹ̀ kuro ninu oku, on ni yio kọ́ kede imọlẹ fun awọn enia ati fun awọn Keferi.


Awọn wọnyi ni kanga ti kò li omi, ikũku ti ẹfũfu ngbá kiri; awọn ẹniti a pa òkunkun biribiri mọ́ de tití lai.


Nitoripe bi Ọlọrun kò ba dá awọn angẹli si ti nwọn ṣẹ, ṣugbọn ti o sọ wọn si isalẹ ọrun apadi, ti o si fi wọn sinu ọgbun òkunkun biribiri awọn ti a pamọ́ de idajọ;


Bi awa ba wipe awa ní ìdapọ pẹlu rẹ̀, ti awa si nrìn ninu òkunkun, awa nṣeke, awa kò si ṣe otitọ:


Omi okun ti nrú, ti nhó ifõfó itiju ara wọn jade; alarinkiri irawọ, awọn ti a pa òkunkun biribiri mọ́ dè lailai.


Ati awọn angẹli ti kò tọju ipò ọla wọn ṣugbọn ti nwọn fi ipò wọn silẹ, awọn ni o pamọ́ ninu ẹ̀wọn ainipẹkun nisalẹ òkunkun de idajọ ọjọ nla nì.


Awọn orilẹ-ède yio si mã rìn nipa imọlẹ rẹ̀: awọn ọba aiye si nmu ogo wọn wá sinu rẹ̀.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan