53 Nwọn si lọ olukuluku si ile rẹ̀.
53 Wọ́n sì lọ olúkúlùkù sí ilé rẹ̀.
Oluwa mu ìmọ awọn orilẹ-ède di asan: o mu arekereke awọn enia ṣaki.
Nitõtọ ibinu enia yio yìn ọ: nigbati iwọ ba fi ibinu iyokù di ara rẹ li amure.
A kó awọn alaiya lile ni ikogun, nwọn ti sùn orun wọn, gbogbo ọkunrin alagbara kò si ri ọwọ wọn.
Nwọn dahùn nwọn si wi fun u pe, Iwọ pẹlu nṣe ara Galili bí? Wá kiri, ki o si wò: nitori kò si woli kan ti o ti Galili dide.
JESU si lọ si ori òke Olifi.
Nigbati a si ti dágbere fun ara wa, awa bọ́ si ọkọ̀; ṣugbọn awọn si pada lọ si ile wọn.