Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:42 - Bibeli Mimọ

42 Iwe-mimọ́ kò ha wipe, Kristi yio ti inu irú ọmọ Dafidi wá, ati Betlehemu, ilu ti Dafidi ti wà?

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

42 Ṣebí Ìwé Mímọ́ ti sọ pé láti inú ìdílé Dafidi, ní Bẹtilẹhẹmu ìlú Dafidi, ni Mesaya yóo ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

42 Ìwé mímọ́ kò ha wí pé, Kristi yóò ti inú irú-ọmọ Dafidi wá, àti Bẹtilẹhẹmu, ìlú tí Dafidi ti wá?”

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:42
17 Iomraidhean Croise  

Salma baba Bet-lehemu, Harefu baba Bet-gaderi.


Oluwa ti bura nitõtọ fun Dafidi; on kì yio yipada kuro ninu rẹ̀, Ninu iru-ọmọ inu rẹ li emi o gbé kalẹ si ori itẹ́ rẹ.


Irú-ọmọ rẹ li emi o gbé kalẹ lailai, emi o si ma gbé itẹ́ rẹ ró lati irandiran,


ẼKÀN kan yio si jade lati inu kùkute Jesse wá, ẹka kan yio si hù jade lati inu gbòngbo rẹ̀:


Sa wò o, ọjọ mbọ, li Oluwa wi, ti emi o gbe Ẹka ododo soke fun Dafidi, yio si jẹ Ọba, yio si ṣe rere, yio si ṣe idajọ ati ododo ni ilẹ na.


Ati iwọ Betlehemu Efrata; bi iwọ ti jẹ kekere lãrin awọn ẹgbẹgbẹ̀run Juda, ninu rẹ ni ẹniti yio jẹ olori ni Israeli yio ti jade tọ̀ mi wá; ijade lọ rẹ̀ si jẹ lati igbãni, lati aiyeraiye.


IWE iran Jesu Kristi, ọmọ Dafidi ọmọ Abrahamu.


Nwọn si wi fun u pe, Ni Betlehemu ti Judea ni: nitori bẹ̃li a kọwe rẹ̀ lati ọwọ́ woli nì wá,


Iwọ Betlehemu ni ilẹ Judea, iwọ kò kere julọ ninu awọn ọmọ alade Juda, nitori lati inu rẹ ni Bãlẹ kan yio ti jade, ti yio ṣe itọju Israeli awọn enia mi.


Nitori a bí Olugbala fun nyin loni ni ilu Dafidi, ti iṣe Kristi Oluwa.


Josefu pẹlu si goke lati Nasareti ilu Galili lọ, si ilu Dafidi ni Judea, ti a npè ni Betlehemu; nitoriti iran ati idile Dafidi ni iṣe,


Ṣugbọn awa mọ̀ ibi ti ọkunrin yi gbé ti wá: ṣugbọn nigbati Kristi ba de, kò si ẹniti yio mọ̀ ibiti o gbé ti wà.


OLUWA si wi fun Samueli pe, Yio ti pẹ to ti iwọ o fi ma kãnu Saulu, nigbati o jẹ pe, mo ti kọ̀ ọ lati ma jọba lori Israeli? Fi ororo kún iwo rẹ, ki o si lọ, emi o rán ọ tọ̀ Jesse ara Betlehemu: nitoriti emi ti ri ọba kan fun ara mi ninu awọn ọmọ rẹ̀.


Ọkan ninu iranṣẹ wọnni si dahùn wipe, Wõ emi ri ọmọ Jesse kan ti Betlehemu ti o mọ̀ iṣẹ orin, o si jẹ ẹni ti o li agbara gidigidi, ati ologun, ati ẹni ti o ni ọgbọ́n ọ̀rọ isọ, ati arẹwa, Oluwa si wà pẹlu rẹ̀.


Samueli si ṣe eyi ti Oluwa wi fun u, o sì wá si Betlehemu. Awọn agbà ilu na si bẹ̀ru nitori wiwá rẹ̀, nwọn si wipe, Alafia ki iwọ ba wá si bi?


Saulu si bi i lere pe, Ọmọ tani iwọ ọmọde yi iṣe? Dafidi si da a li ohùn pe, Emi li ọmọ Jesse iranṣẹ rẹ ara Betlehemu.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan