Biblia Todo Logo
Bìoball air-loidhne

- Sanasan -




Johanu 7:32 - Bibeli Mimọ

32 Awọn Farisi gbọ́ pe, ijọ enia nsọ nkan wọnyi labẹlẹ̀ nipa rẹ̀; awọn Farisi ati awọn olori alufã si rán awọn onṣẹ lọ lati mu u.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Yoruba Bible

32 Àwọn Farisi gbọ́ pé àwọn eniyan ń sọ ọ̀rọ̀ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ báyìí láàrin ara wọn nípa Jesu. Àwọn olórí alufaa ati àwọn Farisi wá rán àwọn ẹ̀ṣọ́ Tẹmpili pé kí wọ́n lọ mú Jesu wá.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac

Bíbélì Mímọ́ ní Èdè Yorùbá Òde-Òní

32 Àwọn Farisi gbọ́ pé, ìjọ ènìyàn ń sọ nǹkan wọ̀nyí lábẹ́lẹ̀ nípa rẹ̀; àwọn Farisi àti àwọn olórí àlùfáà sì rán àwọn oníṣẹ́ lọ láti mú un.

Faic an caibideil Dèan lethbhreac




Johanu 7:32
13 Iomraidhean Croise  

Nigbana li awọn Farisi jade lọ, nwọn si gbìmọ nitori rẹ̀, bi awọn iba ti ṣe pa a.


Ṣugbọn egbé ni fun nyin, ẹnyin akọwe ati Farisi, agabagebe; nitoriti ẹnyin sé ijọba ọrun mọ́ awọn enia: nitori ẹnyin tikaranyin kò wọle, bẹ̃li ẹnyin kò jẹ ki awọn ti nwọle ki o wọle.


Ṣugbọn Peteru tọ̀ ọ́ lẹhin li òkere titi fi de agbala olori alufa, o bọ́ si ile, o si bá awọn ọmọ-ọdọ na joko lati ri opin rẹ̀.


Ṣugbọn awọn ẹlomiran ninu wọn tọ̀ awọn Farisi lọ, nwọn si sọ fun wọn ohun ti Jesu ṣe.


Nitorina awọn Farisi wi fun ara wọn pe, Ẹ kiyesi bi ẹ kò ti le bori li ohunkohun? ẹ wò bi gbogbo aiye ti nwọ́ tọ̀ ọ.


Nigbana ni Judasi, lẹhin ti o ti gbà ẹgbẹ ọmọ-ogun, ati awọn onṣẹ́ lati ọdọ awọn olori alufa ati awọn Farisi, wá sibẹ̀ ti awọn ti fitilà ati òguṣọ̀, ati ohun ijà.


Nitorina nwọn nwá ọ̀na ati mú u: ṣugbọn kò si ẹnikan ti o gbé ọwọ́ le e, nitoriti wakati rẹ̀ kò ti ide.


Nigbana li olori ẹṣọ́ lọ pẹlu awọn onṣẹ, o si mu wọn wá kì iṣe pẹlu ipa: nitoriti nwọn bẹ̀ru awọn enia, ki a má ba sọ wọn li okuta.


Saulu si ran onṣẹ lati mu Dafidi: nigbati nwọn ri ẹgbẹ awọn wolĩ ti nsọtẹlẹ, ati Samueli ti o duro bi olori wọn, Ẹmi Ọlọrun si bà le awọn onṣẹ Saulu, awọn na si nsọtẹlẹ.


Lean sinn:

Sanasan


Sanasan